Blighted Ovum: Obìnrin kan sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tí oyún bàjẹ́ lára rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta

Blighted Ovum: Obìnrin kan sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tí oyún bàjẹ́ lára rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta

Lara awọn ipenija ti obinrin maa n koju nile ọkọ ni ki oyun maa bajẹ lara rẹ ni aimọye igba.

Iru isẹlẹ bayii si ti sọ ọpọ obinrin ni orukọ buruku pe o n jo oyun jẹ tabi pe awọn ọta kan lo wa nidi isẹlẹ naa lai mọ pe aidape ara lo n faa.

Orukọ aidape ara yii ni wọn n pe ni Blighted Ovum eyi to n mu ki oyun ọsẹ mẹjọ si mẹtala maa bajẹ leralera lara obinrin.

Bo se sẹlẹ si Loise Nyagol ree, ẹni to salaye fun BBC nipa ohun toju rẹ nigba ti oyun mẹta bajẹ lara rẹ leralera ati ọna abayọ to gba, titi to fi bimọ.

Bakan naa, onimọ nipa ọmọ bibi kan, Wajiro Njuguna naa salaye ohun to mu ki oyun maa bajẹ lara obinrin atawọn ọna ti wsn le gba dẹkun rẹ.