El Salvador: Wọ́n bá òkú èèyàn mẹ́jọ ní àgbàlá ọlọ́pàá ọkùnrin kan

Awọn onimọ sọ pe o le to oṣu kan ki wọn o to wu awọn oku yooku jade

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Awọn onimọ sọ pe o le to oṣu kan ki wọn o to wu awọn oku yooku jade

Ko din ni oku eeyan mẹjọ ti wọn ba ninu iboji kan to wa ni ile ọkunrin kan to ti fi igba kan jẹ ọlọpaa ni El Salvador.

Awọn alaṣẹ sọ pe o ṣe e ṣe ki oku eeyan tun ṣi wa ninu iboji naa, ti igbagbọ wa pe obinrin tabi ọmọdebinrin lo pọ ju ninu wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe yoo to oṣu kan, ki wọn o to le wu gbogbo oku to wa nibẹ jade.

Bakan naa ni wọn ni igbagbọ pe nkan ti wọn ṣe awari yii tu aṣiri ikọ apaniyan kan to ti n ṣe ijamba lati bi ọdun mẹwaa.

El Salvador ni iwa pipa awọn obinrin tabi ọmọdebinrin, nitori ibalopọ wọpọ si julọ ni Latin America.

Hugo Ernesto Osorio Chávez, ẹni ọdun 51, ni wọn fi si ahamọ nilu Chalchuapa, ninu oṣu yii, nitori pe pa obinrin ẹni ọdun 57 kan, ati ọmọ rẹ obinrin to jẹ ẹni ọdun 26.

Àkọlé fídíò,

Àìsàn jẹ́ kí àwọ̀ ara Amida dàbí ara ẹja

Ọkunrin naa to jẹ ọlọpaa nigba kan jẹwọ pe lootọ ni oun pa iya atọmọ naa.

Wọn ti wadii rẹ ri fun ẹsun ifipabanilopọ.

Amọ, nigba ti awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe abẹwo si ile rẹ to wa ni Ariwa olu ilu orilẹ-ede naa, San Salvador, ko din ni koto meje ti wọn ba. Gbogob rẹ lo si ni oku eeyan ninu, eyi to ṣe e ṣe ki wọn o ti sin wọn lati bi ọdun meji sẹyin.

Wọn si ti sọ pe ayẹwo DNA yoo waye, lati le da awọn oku naa mọ.

ṣaaju ni awọn alaṣẹ sọ pe oku eeyan 24 ni wọn ri, ti ko si si alaye kankan lori nkan to mu ki wọn o pada dinku si mẹjọ.

Ọga Agba ọlọpaa ni orilẹ-ede naa, Mauricio Arriaza sọ fun BBC pe afurasi ọdaran naa sọ pe ori ayelujara ibaraẹnidọrẹ ni oun ti n pade awọn ti oun pa.

"O sọ pe niṣe ni oun ma n ṣeleri fun wọn pe oun yoo mu wọn lọ si orilẹ-ede America."

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Ọkan lara awọn to lọ si ile naa lati wo boya wọn o ri eeyan wọn to ti di awati nibẹ

Ọpọlọpọ eniyan si lo jade lọ si iwaju ile naa ni Ọjọbọ, lẹyin ti iroyin naa jade, lati wo o boya eeyan wọn to ti di awati wa lara awọn ti wọn ri oku wọn.

Obinrin 70 ni akọsilẹ wa pe wọn pa ni El Salvador lọdun to kọja, 111 ni 2019.