Àwọn ọ̀dọ́ agbègbè Busunu ni ẹkùn Savannah ní Ghana ti kọ́ ẹ̀bùn àpò ìrẹsì tí Asofin Samuel Abu pín

Samuel Abu Jinapor

Oríṣun àwòrán, Ghana government/others

Wo ìdí tí àwọ́n ọ̀dọ́ Ghana fi kọ àpò ìrẹsì tí Asofin kan pín fún wọn

Fọnran fidio kan lo jade loju opo ayelujara nibi ti awọn ọdọ kan n da apo irẹsi ti wọn fi ransẹ si awọn ara agbegbe naa gẹgẹ bii ẹbun pada.

Awọn ọdọ naa da apo irẹsi naa pada sinu ọkọ Hilux ti wọn fi gbe e wa fun wọn lọjọ Aiku to kọja.

Ariwo: 'isẹ ni a n fẹ kii se ounjẹ, Samuel Jinaper mu ileri too se fun wa lasiko idibo sẹ'ni wọn n pa bi wọn se n da apo irẹsi naa pada.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awon ileesẹ iroyin abẹle Zaaradio ni pe saaju ni ọma ile igbimọ asofin naa, Samuel Abu Jinaper ti seleri ipese isẹ lọpọ yanturu fun awọn ọdọ naa lasiko eto idibo.

Eyi ni wọn ni ko musẹ losu meje lẹyin to wọle ko to maa pin irẹsi.

Iroyin ni se ni awọn ọdọ naa ba irẹsi naa jẹ ti wọn si daa pada si ọda Asofin to ko wọn ransẹ si wọn.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho: Timi Orokoya ní orin Iléyá tí òun kọ lọ́dún 28 sẹ́yìn, ló padà wá ṣẹ báyìí

Tani ni Samuel Abu Jinapor?

Samuel Abu Jinapor jẹ agbajọrọ.

Odun 2020 lo kọkọ wọile igbimọ Asofin lẹyin to dije dupo pẹlu Adam Mutawakilu ti ẹgbẹ NDC

O ti kọkọ se igbakeji adari ile si Aare Akufo-Addo ni ọdun 2017 si 2020.

O sise gẹgẹ bii minista fun ọrs ilẹ ati nkan alumọni nigba ti Nana Akufo Addo se aare lẹẹkeji.