Paedophile:Arákùnrin kan r'ẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rìnlélógún he lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ pẹlú ọmọ ọjọ méjìlá

Aworan ikoko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arakunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan to ba ọmọ ikoko ọjọ mejila lajọṣepọ ladajọ ti ran lẹwọn ọdun mẹrinlelogun.

Iṣẹlẹ ibalopo yi waye ni agbegbe Annalong ni County Down ni Ireland ni oṣu Kẹsan ọdun 2018.

Adajọ naa sọ pe awọn ko le darukọ ọdaran naa lati le fi daabọ bo ikoko naa amọ o juwe iwa yi gẹgẹ bi eleyi to buru gaan.

O tẹsiwaju pe idajọ ẹwọn ọdun mẹrinlelogun yi di dandan lati le fi ijiya to tọ jẹ arakunrin naa ki wọn si le fi daabo bo araalu.

Wọn gbe ikoko yi lọ si ile iwosan Daisy Hill Hospital ni Newry nitori ifarapa si apa, ori, ẹgungun igbaya rẹ, ẹsẹ ati oju ara lọdun mẹta sẹyin.

Ọjọ mẹtala ni ọmọ naa lo ni ẹka pajawiri ile iwosan Royal Victoria to wa fun itọju awọn ọmọ ti ara wọn ko ba ya.

Ọjọ mẹsan ninu ọjọ mẹtala yi lo fi n gba afẹfẹ oxygen labẹ fẹntilatọ.

''Ẹjọ yi fọwọ kan ni lẹmi''

Esi iwadii kan tawọn oniṣẹ ilera gbe jade sọ pe ara ọmọ naa ti n ya ṣugbọn o wa ninu ewu pe o le ni aisan warapa .

Bẹẹ ni wọn s pe ọmọ naa le ni iṣoro kikọ ẹkọ tabi arun ọpọlọ lọjọ iwaju.

Nibẹrẹ ọdun yi lọdaran ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa sọ niwaju adajọ pe oun jẹbi ibalopọ ati mimu inira ba ọmọ naa.

Ni ọjọ Ẹti ti adajọ gbe idajọ kalẹ o sọ pe arakunrin naa ko tiẹ ni itara iwa to buru jai to wu yi

Àkọlé fídíò,

Ìfipábánilòpọ̀: Abiamọ bú sẹ́kún nígbà tí ọkùnrin kan fi tipá bá ọmọ méjì lòpọ̀

O ni aile gbọ lẹkunrẹrẹ oun to ṣẹlẹ lati ẹnu ọdaran naa jẹ nkan to fọwọ kan ni lẹmi.

Adajọ Stephen Fowler QC sọ pe ọmọ ikoko ti ko le gba ara rẹ kalẹ ni ẹni ti o faragba iṣẹlẹ aburu yi.

''Diẹ lo ku ki ba ku bi kii ba ṣe ti itọju to ri gba.Yoo si pẹ gaan ki awọn ohun to rọ mọ iṣẹl yi to bẹrẹ si ni yọju sita.''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: