"Àlàyé rèé lórí ìpàdé tí wọn ló wáyé láàrin Tinubu àti Wike"

Tinubu ati Wike

Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Tinubu, ti sẹ pe ko si ipade kankan to waye laarin oun ati gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike lorilẹede France.

Laipẹ yii ni Tinubu tẹ baalu leti lọ soke okun lati gunle ijiroro alagbara nibẹ.

Amọ eekan kan ninu  ẹgbẹ APC nipinlẹ Eko, Joe Igbokwe lo ti kede laipẹ yii pe ipade wa laarin awọn oloselu mejeeji naa.

Amọ atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ Tinubu feto iroyin, Tunde Rahman fisita lọjọ Ẹti salaye pe bi o tilẹ jẹ pe agba oselu naa ni ọwọ ati apọnle nla fun gomina Wike, sibẹ, ipade kankan ko waye laarin awọn mejeeji ni France.

“A ti ri fidio kan to gbode lori ayelujara ti ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Eko, fisita pe ipade kan waye lorilẹede Faranse laarin Asiwaju Bola Tinubu ati gomina tipinlẹ Rivers.

O si se pataki ka sọ bi ọrọ naa se ri. Bi o tilẹ jẹ pe lootọ ni Asiwaju Tinubu wa lorilẹ ede France amọ ko si ipade kankan to waye laarin Wike ati Tinubu nibikibi.

Sibẹ, eyi ko yẹ otitọ to wa nilẹ kuro pe oludije fun ipo aarẹ naa ko ni ọwọ nla fun gomina ipinlẹ Rivers.”

Atẹjade naa wa rọ awọn akọroyin lati maa fi idi ootọ iroyin mulẹ pẹlu awọn eeyan to yẹ, ki wọn to lọ sare gbe iroyin sita lati dena iru iroyin eke bayii.

Ẹgbẹ́ òṣèlú Action Alliance gbé Bola Tinubu lọ iléẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Google

Ẹgbẹ oṣelu Action Alliance ni Naijiria ti kesi Ileẹjọ giga ni Abuja lati dẹkun Ajọ INEC pe wọn ko gbọdọ fi orukọ oludije lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu sinu orukọ awọn oludije ni ọdun 2023.

Ẹgbẹ oṣelu AA ni ki wọn paṣẹ fun INEC lati maṣe gbe orukọ rẹ jade ninu iwe orukọ awọn oludije.

Ninu iwe ipẹjọ FHC/ABJ/CS/954/2022,ti wọn fi ṣọwọ si awọn akọroyin ni wọn ti fẹsun kan Tinbu pe niṣe lo yi iwe ẹri to filede pe oun lọ si ile iwe giga ni ọdun 1999.

Wọn ni ayederu iwe eri lati fasiti Chicago lo fun ajọ eleto idibo ni ọdun 1999 to fi le dije du ipo gomina ni ipinlẹ Eko, to si wọle.

Awọn to wa ninu iwe ipẹjọ naa ni Ajọ INEC, APC ati Tinubu pẹlu ẹsun pe awọn ni idaniloju pe Tinubu ko ni gbogbo awọn sabuke to kọ fun ajọ INEC wipe oun ni.

‘’A fẹ ki ileẹjọ sọ wipe Asiwaju Bola Tinubu ṣe ayederu iwe ẹri ni ọdun 1999 lati dije dupo gomina ni ipinlẹ Eko, nitori naa ko ni aṣẹ lati dije du ipo aarẹ ni ọdun 2023.’’.

Amọ wọn ko i tii fi ọjọ lede ti wọn yoo ṣe igbẹjọ naa.

Awọn eniyan ni ileẹjọ wa fun kii ṣe ẹranko, ẹ o ba wa nibẹ - Ẹgbẹ alatilẹyin Tinubu

Alaga Ajọ South West Agenda for Asiwaju 2023, Sẹnetọ Adedayo Adeyeye to n ṣe atilẹyin fun Tinubu ti ni ẹgbẹ oṣelu AA yoo ba awọn ni ileẹjọ.

‘’Ti wọn ba sọ wi pe awọn wa ni ileẹjọ, a o ba wọn nibẹ.’’

Bakan naa ni ẹgbẹ Asiwaju Progressive Forum ni Tinubu yoo gbeja ara rẹ ni ileẹjọ.

Wọn ni awọn eniyan ni wọn ṣe ileẹjọ fun kii ṣe ẹranko nitori naa awọn mejeeji yoo jọ waako labẹ ofin.