MaryGotFit :obìnrin bí ọkùnrin agbírinsápá ṣàlàyé ìdẹ́yẹsí tó ń kojú nídìí iṣẹ́ tó yàn láàyò

Aworan MARYGOFIT

Oríṣun àwòrán, MARY_GOT_FIT/INSTAGRAM

Ọmọ bibi Ghana ati Naijiria ni arabinrin MaryGotFit ti o si jẹ agberinsapa to n gbiyanju kawọn obinrin fi ipa wọn lelẹ ninu iṣẹ naa.

Mary Nyarko lorukọ rẹ gangan ti o si n le ero ọkan rẹ lati di akọsẹmọṣẹ agberinsapa.

Lati igba to ti wa ni nkan bi ọmọ ọdun mejilelogun ni ko ti bojuwẹyin to si ti n tẹpa mọṣẹ to yan laayo yi.

Lẹhinkule ile mama rẹ lo ti kọkọ bẹrẹ si ni fi igo ati apo to rọ iyepẹ sinu rẹ maa fi ṣe igbaradi.

O tẹsiwaju pẹlu lilo aloku taya ọkọ nla ati awọn nnkan miran.

Amọ ṣa ipinnu rẹ lati di agberinsapa yi ko ṣalae wa pẹlu ipenija tirẹ.

Ọrọ to bami ninu julọ ti eeyan sọ si mi

Oríṣun àwòrán, MARY_GOT_FIT/INSTAGRAM

Eeyan kii wa ki o ma koju ipenija tiẹ.

Ninu ọrọ ti Mary Go Fit sọ pe o ba oun ninu jẹ ju ti eeyan sọ si oun ni eleyi ti o ni''eeyan kan sọ fun mi pe ara mi n ri oun lara.O ni mama mi fi oṣu mẹsan ṣofo pẹlu inira ati ijiya ni''

Bẹẹ ni Mary ṣalaye fun akọroyin BBC fAVOUR nUNOO.

O tẹsiwaju pe ''ọrọ naa dunmi gaan, o si wọ mi lara abi ẹda ẹlẹran ara kọ lemi naa ni?."

O ni ohun ko mọ idi ti eeyan yoo kan lanu lati fi da irẹwẹsi ọkan si ọmọ lakeji rẹ lara.

O ni ọrọ naa dun oun pupọ ṣugbọn oun ni lati fi ọkan gbe kuro lara ni.

''Awọn eeyan maa n sọ ọrọ buruku si ẹda ẹgbẹ wọn ṣugbọn mi o le sọ pe ki n na awọn eeyan yi.Nitori wọn a maa sọ pe obinrin aniṣulapa bi ọkunrin tun ti da bantẹ iya fawọn eeyan.''

Oríṣun àwòrán, MARY_GOT_FIT/INSTAGRAM

Nkan tawọn eeyan ko mọ nipa awọn obinrin agberinsapa

Gẹgẹ bi Mary ti ṣe sọ, ọpọ lo maa n ro pe awọn obinrin agberinsapa maa n buru gaan.

''ọpọ wa la rọ bi ẹkọ.Awa naa a maa sunkun daada.''

Nitori naa bi eeyanba ṣe nkan to dun mi ile idaraya gym ni mo ti maa n gbe kuro lọkan nipa gbigbe irin.

O ni oun kii saba ba wọn lọ si ode tabi isinku ni Ghana nitori oun kii ri aṣọ lati wọ lọ si iru ode bayi ti yoo bo gbogbo ara tan.

O ni awọn eeyan le maa sọ fawọn obinrin mi pe wọn rẹwa ti wọn ba wọ aṣọ alapa penpe ṣugbọn ti iru mi ba fi le wọ aṣọ to fi ara silẹ, wọn a maa beere pe ''kini eleyi,ki lo de ti ara rẹ fi wa dabi ti ọkunrin?''