INEC kọminú lórí bí àwọn èèyàn kan ṣe dáná sun ọ́ọ́fìsì wọn nílùú Enugu

INEC banújẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n dáná sun ọọ́físì rẹ̀ ní Enugu

INEC office Enugu

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria

Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, ti ni inu oun bajẹ bi awọn eeyan kan ṣe n dana sun ọọfisi oun, paapaa eyii to waype kẹyin niluu Enugu.

Akọwe ajọ naa, Rotimi Oyekanmi, sọ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Punch pe o ye ki awọn ọmọ Naijiria daab bo dukia ajọ naa fun anfani ara wọn.

Oyekanmi rawọ ẹbẹ yii lẹyin ti awọn eeyan kan dana sun ọọfisi ajọ naa to wa ni ijọba ibilẹ Ariwa Igboeze, ni ipinlẹ Enugu.

Iṣẹlẹ naa to waye lalẹ ọjọ Aiku ni iroyin ni o ba ọọfisi naa jẹ, to fi mọ awọn oun elo to ṣe pataki ti wọn n lo ni ọọfisi ajọ naa.

Awọn afurasi bori awọn ẹṣọ alaabo ọọfisi INEC

Ọga agba to n ri si ọrọ iroyin ati itaniji ni INEC, Festus Okoye sọ pe awọn afurasi naa bori awọn ẹṣọ alaabo to n sọ ọọfisi naa, ti wọn si wọle sibẹ lati sọ ina si ọọfisi ọhun.

Okoye ni bo tilẹ jẹ pe ko si ẹnikẹni to ba iṣẹlẹ naa lọ, apoti idibo 748, ati apoti ti awọn oludibo ti maa n tẹ ika 240 ni wọn ko lọ, to fi mọ awọn ohun elo mii ti ina jo.

O ni “Ajọ naa n gbiyanju lati mọ irufẹ ipo ti ẹrọ ti wọn fi n ṣe iforukọsilẹ oludibo wa, atawọn kaadi idibo ti awọn eeyan ko tii gba ti a ko pamọ sinu apoti ti ina ko le jo.”

Ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, alukoro ileẹsẹ ọlọpaa Enugu, Daniel Ndukwe ni awọn ti bẹrẹ iwadii.

Ẹwẹ, INEC ti sọ pe awọn ọta ijọba awarawa lo wa nidi ikọlu ọhun.

Akọwe ajọ naa, Rotimi Oyekanmi, ni “Ikọlu lemọ-lemọ ti awọn kan n ṣe si ̣ọọfisi INEC n kọ wa lominu, paapaa eyii ti wọn ṣe si ipinlẹ Enugu yii.”

“A ti fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, a si gbagbọ pe wọn yoo ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ”

“Amọ ako ni jẹ ki awọn ikọlu naa di wa lọwọ lati ṣiṣẹ wa ni igbaradi fun eto idibo gbogbogbo ti yoo waye lọdun 2023.