Jimi Olubunmi-Adewole: Akínkanjú ọmọ ọdun 20 tó dóòlà ẹ̀mí èèyàn pàdánù tiẹ̀ nínú odò Thames

Aworan Folajimi Olubunmi Adewole

Oríṣun àwòrán, GOFUNDME

Abajade iwadii ti ijọba ṣe ti ṣapejuwe nkan ti arakunrin kan ṣe gẹgẹ bi ''iwa akikanju'' nipa pe o bẹ sodo lati doola obinrin kan ninu omi Thames nilẹ Gẹẹsi.

Orukọ arakunrin naa a si maa jẹ Folajimi "Jimi" Olubunmi-Adewole.

Ẹni ogun ọdun yi n dari lati ibiṣẹ ni nigba to ri obinrin ti ko mọ ri yi ninu omi.

Ko ṣe iye meji to si bẹ sodo lati doola rẹ.

Oun ati eeyan kan Joaquuim Garcia ni wọn jijọ bẹ sodo ṣugbọn obinrin naa ati Joaquim lo ribi jade lodo.

Lẹyin wakati mẹfa, awọn oṣiṣẹ adoola ri oku arakunrin ti awọn eeyan mọ si ''Jimi'' lẹba afara London.

Igbakeji oluyẹwo oku, Dokita Julian Morris sọ ni ile ẹjọ oluyẹwo oku pe ''Ofo nla ni iku arakunrin yi jẹ, ẹni to fẹ ṣe iranwọ lasiko pajawiri fun araalu kan to ja sodo Thames''

Dokita Julius tẹsiwaju pe ''igboya to ni lati bẹ sodo doola ẹni ti ko mọ lalẹ jẹ nkan iyalẹnu.''

O ni ''ọpọ ni yoo maa sọ pe o ṣeeṣe ki emi naa hu iru iwa to wu yi ṣugbọn diẹ ni yoo niigboya lati le ṣe.''

O tubọ ṣalaye fun ileẹjọ yi bi Olubunmi ṣe n rin lọ sile pẹlu ọrẹ rẹ Bernard Kosia lẹyin ti wọn pari iṣẹ tan.

Arakunrin Kosia sọ pe awọn ọkunrin meji kan to wa nibẹ lo ta awn lolobo pe arabinrin naa ti ja sodo.

Oríṣun àwòrán, Bernard Kosia

Lẹyin ti wọn gbọ igbe obinrin naa to n pariwo pe '' mi o mọ ọ wẹ, mo maa ku''

awọn ọrẹ mejeeji yi pe ọlọpaa lori ago.

Ọrẹ Jimi, Bernard sọ fun ọlọpaa pe ''Jimi ṣa n sọ pe a ni lati doola arabinrin yi, ko gbọdọ ku''

Ayẹwo oku Jimi ti wọn ṣe fihan pe omi to ko si lọna ọfun lo ṣekupa.

Wọn lawọn ko ri pe nkan miran ṣe idiwọ to ṣokunfa iku rẹ yatọ si eleyi.

Arakunrin Garcia ti wọn jijọ ko sodo sọ pe o soju mi koro kan ni arabinrin naa wa ninu omi to si n pariwo kawọn eeyan ran an lọwọ.

O ni lẹyin tawọn dikan ni oun ati Jimi bẹ sodo ti ọgbẹni Garcia si ribi de ọdọ obinrin naa.

Wọn ko ri Olubunmi- Adewole laaye mọ lẹyin to ko siodo yi.

Ileeṣẹ ọlọpaa ilu London pada wa fi ami da Jimi lọla ni imọriri iwa akin to hu ati ni iranti akikanju yi.