Ìdíje bọ̀ọ́lù àwọn obìnrin, WAFCON 2022 gbérasọ ní Morocco

aworan bọọlu to ni akọle WAFCON lara

Oríṣun àwòrán, cafonline

Ọjọ keji, oṣu Keje, ọdun 2022, ni idije fun ife ẹyẹ bọọlu awọn obinrin ni Afrika, Women's Africa Cup of Nations, yoo bẹ̀rẹ̀ ni orile-ede Morocco.

Ti ọdun yii si ni igba akọkọ ti orile-ede mejila n kopa ninu idije naa.

Saaju asiko yii, orile-ede mẹ́jọ lo ma ń kopa.

Bakan naa lo jẹ pe igba àkọ́kọ́ re e ti Morocco gbalejo idije naa. Papa ìṣeré mẹta ni yoo ti waye, n'ilu Rabat olu ilu Morocco, ati ilu Casablanca laarin ọjọ keji oṣu Keje, si ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keje.

Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ akọkọ lati ṣide yoo waye laarin Morocco ati Burkina Faso ni papa isere Prince Moulay Abdellah n'ilu Rabat.

Oríṣun àwòrán, caf

Ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Falcons, lo gba ife naa ni idije mẹta to kọja, wọn si ti gba a nígbà mẹsan-an, ninu igba mọkanla ti idije naa ti waye.

Ipin C ni Naijiria wa ninu idije ti ọdun yii. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ yoo waye lọjọ Aje pẹlu orile-ede South Africa.

Lẹyin naa ni wọn o koju Botswana ati Burundi.

Ohun kan to jẹ mímọ̀ ni pe lati ìbẹ̀rẹ̀ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́, ni Super Falcons ti ma n gba jọba idije.

Àwọn agbabọọlu Naijiria to n sisẹ nilẹ okeere, pọ laarin àwọn ọmọ ikọ Super Falcons.

Lara wọn ni Asisat Oshoala, ọmọ ẹgbẹ́ agbabọọlu Spain. Oun naa ni balogun ikọ Super Falcons.

Ni opin idije WAFCON 2022 yii, ẹgbẹ́ agbabọọlu orile-ede to ba bori yoo ni anfaani lati kopa ni idije ife agbaye lọdun to n bọ.

Bakan naa, orile-ede mẹrin to ba de ipele to kangun si aṣekagba, semi-final, yoo ni anfaani lati lọ si Australia ati New Zealand.

Ẹgbẹrun lọ́nà ẹẹdẹgbẹta Dọla ni ẹ̀bùn owo ti orile-ede to ba borí ni WAFCON 2022 yoo gba.