Iléọjọ́ fòfin dé ìyọnípò Rauf Olaniyan tó jẹ́ igbákejì Seyi Makinde ní Oyo

Rauf Olaniyan

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán,

Ile aṣofin bẹ̀rẹ̀ igbeṣẹ lodi si igbakeji gomina, lẹyin to kuro ninu ẹgbẹ́ oṣelu PDP to gbé wọlé, to si darapọ mọ APC

Oyo Deputy impeachment: Iléejọ́ kéde pé wọn kò lè yo Rauf Olaniyan nípò igbákejì gómìnà Oyo lásìkò yìí

Ile éjọ́ giga ni Ibadan ni ipinle Oyo ti dajo lori ejọ́ ti igbakeji gomina ipinle Oyo, Onimo erọ Rauf Olaniyan pe.

Adajo Akintola Ladiran to gbọ́ ejọ́ naa fofin de igbesẹ́ awọn ọmọ ile igbimọ asofin ipinle Oyo ti wọn n gbero yiyọ igbakeji gomina Seyi Makinde kuro nipo leyin to fi egbẹ́ oselu PDP to gbe e wole sile.

Adajo ni pe o seese ki awon ọmọ ile igbimo asofin bẹ̀rẹ̀ igbese bi o ti ye sugbon won nilo lati gbe igbese to ye labe ofin ki ofin to faaye gba eyi tabi bẹ́ẹ̀kọ́.

Oríṣun àwòrán, Others

Loni, ojoRu ni Adajo Akintola so eyi nile ejọ́ giga Court 7 to wa ni agbegbe Ring Road nilu Ibadan to je olu ilu ipinle Oyo

O ni ki ohun gbogbo wa bẹ́ẹ̀ titi igbẹ́jọ́ naa yoo fi pari bi o ti ye labe ofin.

Oludari eka ofin ipinle Oyo, Olabanji lo saaju awon agbejọ́ro awon omo ile igbimo Asofin Oyo nigba ti Agbejoro Afolabi Fashanu SAN saaju ikó Olaniyan.

Igbákejì Seyi Makinde gbé ilé aṣòfin Oyo lọ sílé ẹjọ́ kí wọ́n má bàa yọ́ nípò

Igbakeji gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ ẹ̀rọ Rauf Olaniyan, ti bẹ ile ẹjọ́ giga ijọba ipinlẹ naa, lati fi ofin de igbeṣẹ ti ile asofin n gbe lati yọ ọ nipo.

Saaju ni aṣofin mẹrinlelogun ninu awọn mejilelọgbọn fi ẹ̀sùn marun-un kan Olaniyan.

Àwọn ẹ̀sùn naa ni iwakiwa, aṣilo ipò, inakuna, fifi isẹ silẹ lai ṣe, ati afojudi.

Wọn si fun ni ọjọ meje, lati dahun iwe ẹ̀sùn naa.

Àwọn aṣofin sọ pe igbeṣẹ ti àwọn n gbe wa ni ibamu pẹlu ofin ọdun 2011, abala 188 rẹ.

Iroyin sọ pe igbakeji gomina ti fi esi ransẹ si àwọn asofin naa lori awọn ẹ̀sùn ti wọn fi kan án, nipasẹ agbẹjọro rẹ.

Ile aṣofin naa si sọ pe àwọn ti ri i gba.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu ileeṣẹ redio kan n'ilu Ibadan, olori igbimọ to wa fun eto ibanisọrọ nílé aṣofin naa, Kazeem Olayanju sọ pe àwọn yoo bẹ̀rẹ̀ ijiroro lori ọrọ igbakeji gomina lọjọru.

Àmọ́ ọjọ́ Iṣẹgun ni Olaniyan lọ sile ẹjọ́, pe ko fi ofin de awọn aṣofin ki wọn maa ba yọ ọ nipo.

Nibi igbẹjọ naa ni Onidajọ Ladiran Akintola ti sun un si Ọjọru.

Adajọ si tun paṣẹ pe ki akọwe ile ẹjọ́ fi igbẹjọ naa to olori ile aṣofin ati akọwe ile leti.

Ile aṣofin bẹ̀rẹ̀ igbeṣẹ lodi si igbakeji gomina, lẹyin to kuro ninu ẹgbẹ́ oṣelu PDP to gbé wọlé, to si darapọ mọ APC lọsẹ díẹ̀ sẹ́yìn.