Gba “Yahoo boy” sílé rẹ kí o fi ẹ̀wọ̀n ọdún 15 jura, EFCC  kìlọ̀ fún àwọn oníle

Gba “Yahoo boy” sílé rẹ kío fi ẹ̀wọ̀n ọdún 15 jura, EFCC  kìlọ̀ fún àwọn oníle

EFCC

Oríṣun àwòrán, @EFCC

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC, ti kilọ pe o ṣeeṣe ki awọn onile to ba gbe ile wọn fun awọn ọdọ to n ṣe Yahoo fi ẹwọn ọdun marundinlogun jura.

EFCC  lo sọ ọrọ naa ṣaaju ifọrọwerọ kan pẹlu awọn araalu nibi eto kan ti wọn pe #EFCCConnect loju opo Twitter.

Lara awọn ọga agba ajọ naa, Sylvanus Tahir ati Cosmos Ugwu lo sọrọ lori akọle naa nibi ifọrọwerọ ọhun.

Ti ẹ ko ba gbagbe EFCC ti kọkọ kilọ fun awọn onile to n gbe ile wọn silẹ fun awọn ọmọ yahoo lati dẹkun ṣiṣẹ bẹẹ.

Awọn onile itura naa ko gbẹyin

Ṣaaju ni alaga ajọ naa, Abdulrasheed Bawa ti ṣe ipade pẹlu awọn onile itura niluu Ilorin lati ṣe idanilẹkọọ fun wọn nipa awọn ewu to wa ninu ki wọn maa fun awọn ọmọ Yahoo ni yara nile itura wọn, ati ọna lati gbogun ti iwa jibiti ori ayelujara.

Ọkan lara awọn adari EFCC mii, Micheal Nzekwe ni ajọ naa n kọminu lori bi awọn to n ṣowo ile itura ṣe n padi apo pọ pẹlu awọn ọmọ Yahoo naa.

Nzekwe fẹsun kan awọn kan lara awọn oniṣowo ọhun pe wọn n ṣatilẹyin fun awọn afurasi oni jibiti naa ni bi wọn ṣe n fun wọn nile ati yara.

O ni iwa yii lodi si abala kẹta iwe ofin to tako iwa jibiti lilu ti wọn gbe kalẹ lọdun 2006.

O tẹsiwaju pe “Abala naa kede ẹwọn ọdun marun un si marundinlogun lai si aṣayan lati san owo itanra fun ẹnikẹni ti wọn ba n lo ile rẹ fun iwa ọdaran to wa labẹ abala naa.”

Nzekwe ni ofin naa ko naani boya ile itura ni tabi ileegbe.

EFCC ti kilọ fun awọn to n ṣowo ile itura lati maa bere iṣẹ ti awọn onibara wọn n ṣe lọwọ wọn ki wọn to fun wọn ni yara.