Cristiano Ronaldo kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí wọ́n fi kàn án – Iléẹjọ́ Amerika

Cristiano Ronaldo: Iléẹjọ́ Amerika ní Cristiano Ronaldo kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí wọ́n fi kàn án

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbẹjọro agba lorilẹede Amerika ti fi ọwọ da ẹjọ ti wọn pemọ agbabọọlu Cristiano Ronaldo nu.

Ẹsun ti arabinrin Kathryn Mayorwa fi kan agbabọọlu ikọ Manchester United nipe o fi ipa ba oun lopọ ni ile itura Las Vegas ni ọdun 2009.

Amọ Ronaldo ni oun ko jẹbi ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan oun.

Arabinrin Mayorga oun ni o kọkọ gba lati dakẹ jẹ lori ẹsun naa ni ọdun 2010, amọ ọpọlọpọ miliọnu owo ilẹ okeere ju iye owo to to $375,000 (£304,000) ti wọn fun lo n bere fun.

Amọ ni ọdun 2018 lo tun ṣi igbẹjọ naa pada lati ko ẹjọ naa wa si gbangba.

Amọ Agbẹjọro rẹ ni wọn fẹsun kan pe o dabaru eto igbẹjọ nipa lilo awọn ohun ti ko lẹtọ (confidential)  ti ko yẹ ko lo lọna aitọ.

Wọn fẹsun kan agbẹjọro naa pe ọna ẹburu to gba naa ni ipa buburu lara Ronaldo.

Nitori naa ni adajọ da ẹjọ naa nu nitori o gba ọna ẹburu lati fi ko ẹsun rẹ jọ.

Bi o tilẹ jẹ pe Ronaldo ko sọ wi pe oun ko mọ obinrin naa ri, ohun to n sọ nipe oun ko fi ipa ba a lopọ ni ọdun 2009 ni Las Vegas.

Ati wi pe ajọmọ awọn mejeeji ni nkan to waye laarin wọn, kii ṣe afipaṣe.