Portable yọjú sí àgọ́ ọlọ́pàá, ẹ wo ibí tí ọ̀rọ̀ kángun sí

Aworan Portable ati ami idanimọ ileeṣẹ ọlọpaa

Yoo yọju koni yọju, gbajugbaja akọrin takasufe nii Habib Okikiola ti ọpọ mọ si Portable ti pada yọju si agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun.

Eyi ko ṣẹyin ipe ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita fun pe ki o wa wi tẹnu rẹ nipa fọnran fidio kan nibi ti oun ati awọn eeyan kan ti da bantẹ iya farakunrin kan.

Ileeṣẹ ọlọpaa lo fidi ọrọ yi mulẹ lati ọwọ alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun,Abimbola Oyeyemi ninu taẹjade kan.

Adugbo Elewe ẹran ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe Portable ati awọn ọmọ lẹyin rẹ kan ti lu arakunrin ti wọn pe orukọ rẹ ni DJ Chicken.

Wọn ni nkan bi ago marun irọlẹ ni Portable ati baba rẹ yọju si agọ ọlọpaa to wa ni Eleweẹran.

Ki lo ṣẹlẹ nigba to de agọ ọlọpaa

Gẹgẹ bi Oyeyemi ti ṣe sọ, kete ti Portablle de agọ ọlọpaa Eleweran ni Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ogun ni ki wọn gbe lọ si ẹka to n risi ọrọ ẹhonu araalu.

Nibẹ ni awọn ọlọpaa ti fọrọwalẹnuwo lori ipa to ko ati ohun to mọ nipa iṣẹlẹ to waye nibi ti wọn ti lu arakunrin to wa ninu fọnran fidio taa n wi yi.

Oyeyemi tẹ siwaju pe nitori ti ẹsẹ naa jẹ eleyi ti wọn le gba oniduro rẹ,awọn ni lati tuPortable silẹ pe ko maa lọ sile lẹyin ti oniduro rẹ loun yoo mu wa sọdọ ọlọpaa nigba kugba ti wn ba fẹ ko yọju.

Bakan naa lo ni iyansẹlodi awọn oṣiṣẹ ijọba ni ipinlẹ Ogun ṣe idiwọ lati le tẹsiwaju pẹlu ọrọ ọhun.

Oríṣun àwòrán, Instagram/portablebaeby

Wọn ni ki ẹni ti wọn lu ninu fidio naa yọju

Ẹwẹ ileeṣẹ ọlọpaa fi kun pe awọn ti fi iwe pe arakunrin ti wọn da bantẹ iya fun ninu fọnran fidio to lu sita yi naa ko yọju si agọ ọlọpaa.

Oyeyemi sọ pe awọn n reti rẹ lati wa wi tiẹ naa ki awọn baa le ribi ṣe iwadii awọn lẹkunrẹrẹ.

Bi a ko ba gbagbe, fọnran fidio ibi ti Portable ati awọn eeyan kan ti da bant ẹ iya farakunrin yi lou oju opo ayelujara pa laipẹ yi.

Ninu rẹ, a gbọ ti Portable paṣẹ fawọn ti wọn jijọ duro pe ki wọn da sẹria fun arakunrin taa n wi yi.

Ọpọ eeyan lo bẹnu atẹ lu iwa yi eleyi to mu ki ieeṣẹ ọlọpaa fi ikede sita pe ki Portable fun ara rẹ yọju si agọ ọlọpaa to wa ni tosi rẹ lati wa ṣalaye idi ti o fi ni ki wọn lu arakunrin naa.