Bayern Munich ra Sadio Mane lọ́wọ́ Liverpool pẹ̀lú £35 mílíọ̀nù

Sadio Mane di aṣọ Bayern Munich kan mu

Oríṣun àwòrán, Bayern Munich

Gbajumọ atamatase ikọ agbabọọlu Liverpool, Sadio Mane ti fi ikọ naa silẹ lọ ree darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọ̀lu Bayern Munich lorilẹede Germany.

Miliọnu marundinlogoji ni Bayern ra Mane lọwọ Liverpool, yoo si lo ọdun mẹta labẹ adehun naa.

Igba meji ọtọọtọ ni Liverpool da owo ti Bayern Munich kọkọ gbe kalẹ lati fi ra Mane ki idunadura wọn to wọ.

Sadio Mane, agbabọọlu ọmọ orilẹede Senegal naa ṣalaye pe, “Asiko yii gan ni igba to yẹ fun ipenija tuntun yii”

Mane darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool lati Southampton lọdun 2016 lẹyin ti Liverpool san miliọnu mẹrinlelọgbọn pọun.

Laarin ọdun mẹfa to fi wa ni Liverpool, ọgọfa goolu ni Mane gba si awọn ni ifẹsẹwọ̀nsẹigba ti mọkandinlaadọrin.

Mane kopa to jọju ninu bi Liverpool ṣe gba ife ẹyẹ Champions leagueati Premier league. Oun lo si tun gba goolu to fun orilẹede rẹ, Senegal ni ife ẹyẹ bọọlu ilẹ Afirika, AFCON loṣu keji ọdun 2022.