Ẹ wo bí wọ́n ṣe bẹ́ orí ènìyàn nitori ó sọ ọ̀rọ̀ òdì sí Anabi Muhammed (SAW)

Ina to n jo

Oríṣun àwòrán, @INA

India Udaipur: Wọ́n bẹ́ orí télọ̀ nitori ó sọ ọ̀rọ̀ òdì sí Anabi Muhammed (SAW)

Ija ẹsin ti bẹ silẹ ni ipinlẹ Rajasthan ni India lẹyin ti wọn bẹ ori arakunrin ẹya Hindu nitori o satilẹyin fun isọrọ odi si Prophet Muhammed.

Ẹni ti wọn pa naa to jẹ aranṣọ telọ ni orukọ rẹ n jẹ Kanhaiya Lai, ti awọn ẹlẹsin musulumi meji pa, ti wọn si tun gbe si ori ẹrọ ayelujara.

Wọn ni pipa ti awọn paa ni pe o ṣe atilẹyin fun ọrọ ti oloṣelu kan sọ tako Prophet Muhammmed.

Niṣe ni wọn wọ ṣọọbu arakunrin naa, ti wọn si ṣebi ẹni pe awọn fẹ ranṣọ ki wọn to ṣekupa a.

Nibayii ijọba ti wọgile lilo oju opo ayelujara ati ipejọpọ eniyan ni ọgọọrọ.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ti fi panpẹ mu awọn meji ti wọn darukọ ara wọn ninu fidio ọhun.

Ijọba ilẹ India si rọ awọn akoroyin lati maṣe ṣe apinka fidio naa.

India anti-Prophet Protest: Ilé àwọn Musulumi di wíwó lẹ́yìn ífẹ̀họ́núhàn tako ìsọ̀rọ̀ òdì sí Prophet Muhammed

Oríṣun àwòrán, Google

Ilé àwọn Musulumi di wíwó lẹ́yìn ífẹ̀họ́núhàn tako ìsọ̀rọ̀ òdì sí Prophet Muhammed

Awọn alaṣẹ ni agbegbe Uttar Pradesh ti wo awọn ile palẹ to jẹ ti awọn Musulumi lorilẹede India.

Awọn ti wọn wo ile wọn palẹ naa lo niiṣe pẹlu ifẹhọnuhan ọlọgọọrọ to gbale kan lorilẹede naa, lẹyin ti awọn kan sọrọ odi si Prophet Muhammed.

Ifẹhọnuhan ti wọn n ṣe kaakiri naa lo da rogbodiyan silẹ kaakiri awọn ipinlẹ lorilẹede ọhun.

Ọrọ ti awọn meji ninu awọn oṣiṣẹ agba ninu ẹgbẹ oṣelu BJP sọ nipa Prophet Muhammad lo mu ki awọn araalu to jẹ Musulumi binu ti wọn si bẹrẹ sini ṣe ifẹhọnuhan.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ osẹelu BJP, Nupur Sharma ati agba osẹlu miran Naveen Jindal ni wọn sọrọ kubakugbe nipa Muhammad naa.

Amọ ifẹhọnuhan naa da ija igboro, ti awọn kan siba ọja ati ohun ini awọn eniyan jẹ.

O kere tan ileeṣẹ ọlọpaa ti fi panpẹ ọba mu ọọdunrun eniyan.

Awọn alaṣẹ naa wo awọn ile ẹlẹsin Musulumi mẹta palẹ ni opin ọsẹ lẹyin ti wọn sọ wi pe ọna ẹburu ni wọn gba kọ ile naa.

Amọ awọn onile naa ni kọ si otitọ ninu ẹsun naa.

Wiwo ile wọn naa mu ki ẹgbẹ oṣelu alatako lorilẹede naa fi ẹsun kan ijọba apapọ ti Olotu ijọba Yogi Adityanath ṣe adari fun pe, wọn n ṣe ikọlu si awọn Musulumi ti ẹsin wọn kere lorileede naa, ti kii ṣe ẹsin Hindu to jẹ gboogi nibẹ.

Lati ọdun 2014 ni ija ẹlẹsinmẹsin ti n bẹ silẹ lorilẹede India, lẹyin ti ẹlẹsin Hindu ni ẹgbẹ oṣelu BJP bọ si ipo adari orilẹede naa.