Wo ìgbésẹ̀ tí Falana gbé láti ṣàfikún ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Adedoyin lórí ikú Timothy Adegoke àti ohun tí àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ ṣe

Falana gbé ìgbésẹ̀ láti ṣàfikún ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Adedoyin lórí ikú Timothy Adegoke àmọ́...

Rhaman Adedoyin

Agbẹjọro molẹbi Timothy Adegoke to ku sile itura Hilton nile Ife, Femi Falana, SAN, ti gbe igbesẹ lati ṣafikun awọn ẹsun ti wọn fi kan ẹni to ni ile itura naa, Ramon Adedoyin.

Igbesẹ yii lo waye ni bi igbẹjọ naa ṣe n tẹsiwaju niluu Osogbo.

Falana, ti Fatima Adesina ṣoju fun nile ẹjọ ọhun rọ ile ẹjọ naa lati gba awọn laye lati ṣe afikun ẹsun ti wọn fi kan Adedoyin.

Ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii ni wọn kọkọ gbe ẹbẹ afikun ẹjọ naa siwaju adajọ.

Lẹyin naa ni wọn fi iwe kan kalẹ, lati ṣatilẹyin fun afikun ẹsun naa.

Gẹgẹ bii ohun ti agbẹjọro to ṣoju Falana sọ, abala kinni si ikọkandilọgbọn iwe ti ikọ olujẹjọ pe tako afikun ẹsun naa ko ni gbomgbo.

Agbẹjọro Adedoyin bẹ ile ẹjọ lati da afikun ẹsun naa nu

Ẹwẹ, agbẹjọro Adedoyin atawọn afurasi to ku, Kehinde Eleja, tako afikun ẹsun naa ti ikọ agbẹjọro Femi Falana pe.

Eleja sọ pe adajọ ko le gbọ ẹsun ti wọn fi kan Adedoyin atawọn afikun ẹsun ti wọn gbe wa lasiko kan naa.

Agbẹjọro Adedoyin ni afikun ẹjọ naa ko le fẹsẹ mulẹ nitori ijọba apapọ lo gbe ẹjọ akọkọ wa sile ẹjọ l’Osogbo, kii ṣe ijọba ipinlẹ.

Wọn ni ile ẹjọ ko le paarọ ẹjọ naa tabi ko ṣe afikun rẹ nigba ti ẹjọ kan ti wa nilẹ nitorio pe “Ẹni to gbe afikun ẹjọ naa wa to si tun buwọlu iwe rẹ ko gba asẹ lati ọdọ agbẹjọro agba.”

Falana tako awijare agbẹjọro Adegoke

Amọ ikọ olupẹjọ tako ọrọ naa pe ikọ olujẹjọ ko lẹtọ lati maa paṣẹ fun ile ẹjọ nipa iye ẹjọ to le gbọ.

Lati kin awijare rẹ nidi, agbẹjọro Falana mẹnuba abala 163 iwe ofin to ni ṣe pẹlu iwa ọdaran ati igbẹjọ to waye laarin Uguru ati ijọba lọdun 2022, o si rọ ile ẹjọ lati ko awijare ikọ olujẹjọ nu.

Ẹwẹ, adajọ agba ipinlẹ Osun, Oyebola Adepele-Ojo to n gbọ ẹjọ ọhun sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2022 yii fun itẹsiwaju.