Ìgbà méjìlá tí Super Falcons kojú South Africa ní WAFCON, tí wọn sì dáṣọ ìyà sí wọn lọ́rùn

Awọn agbabọọlu Super Falcons

Oríṣun àwòrán, nff

Ninu idije bọọlu afẹsẹgba to jẹ ti awọn obinrin ilẹ̀ Afrika tó n waye lọwọ ni orile-ede Morocco, ọjọ Aje, ọjọ́ kẹrin, oṣu Keje, ni ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons yoo gba ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ pẹlu orile-ede South Africa.

Papa ìṣeré Prince Heritier Moulay El Hassan, n'ilu Rabat, ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yoo ti waye laago mẹfa irọlẹ.

Igba àkọ́kọ́ kọ re e ti awọn mejeeeji n koju ara wọn.

Ni gbogbo igba ti wọn ba pade lori papa, lo ma n gbona janjan bi ẹ̀kọ.

Eyi ko sẹ́yìn bo ṣe jẹ́ pe ẹgbẹ́ agbabòọlu mejeeji, Super Falcons ati Bayana Bayana, lo jẹ ogbontarigi ninu bọọlu gbigba.

Àmọ́ o, agba lẹtù, ọmọde lawó. Ninu igba mọkanla tí idije WAFCON ti waye, igba mẹsan-an ni Naijiria gba ife ẹyẹ.

Ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo iye igba ti South Africa ati Naijiria ti koju ara wọn:

March 4, 1995: Nigeria 4-1 South Africa

Oríṣun àwòrán, other

Ọdún naa ni igba akọkọ ti ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji koju ara wọn ninu idije bọọlu awọn obinrin ni Africa.

Ewuro ayo mẹrin si odo ni Naijiria gbo si South Africa lẹ́nu, ni papa ìṣeré n'ilu Ibadan.

Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni abala akọkọ ni ipele aṣekagba idije WAFCON lọdun 1995.

Ọdún naa paapaa ni igba àkọ́kọ́ ti Bayana Bayana kopa ninu idije naa. Boya nitori naa ni Naijiria fi lu wọn lalu bolẹ.

Naijiria ko fi mọ nibẹ, nigba ti wọn tun jọ pade n'ilu Johannesburg lorile-ede South Africa, ami ayo meje si ẹyọkan ni Naijiria fi fọ́ South Africa mọ ilé baba wọn.

November 25, 2000: Nigeria 2-0 South Africa

Oríṣun àwòrán, caf

A fi bi ẹni pe wọn fi ẹgba iya le Super Falcons Naijiria lọwọ lati ma a fi lu South Africa ni.

Ninu idije wafcon to tun waye lọdun 2000, wọn tun jọ pade.

South Africa gbiyanju, wọn faraya bii ki wọn o gba ẹsan ìyà meji àkọ́kọ́, àmọ́ Naijiria tun rún wọn mọ́lẹ̀ nilẹ baba wọn, nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to waye n'ilu Boksburg.

Àwọn agbabọọlu Naijiria méjì,Olaitan Yusuf and Stella Mbachu lo rọ̀jò iya le Bayana Bayana lori.

 

December 18, 2002: Nigeria 5-0 South Africa

Oríṣun àwòrán, other

Naijiria ati South Africa pade fun igba kẹrin lọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2002, ni idije wafcon.

Ipele semi-final ni wọn ti pade, lẹyin ti Bayana Bayana borí ni ìpín B, nibi ti wọn wa pẹlu Cameroon, Angola, ati Zimbabwe.

Papa ìṣeré to wa n'ilu Warri, nipinlẹ Delta, ní Super Falcons ti lọ wọn mọlẹ bi ata irẹsi eléwé.

November 3, 2006: Nigeria 2-0 South Africa

Oríṣun àwòrán, other

Fun igba akọkọ, ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji pade ni ibẹrẹ pẹpẹ idije WAFCON lọdun naa.

Naijiria lo bori.

Wọn tun jọ pade fun igba kejì ninu idije naa ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to kẹhin ni ìpín tí wọn pin wọn si, group stage.

Ami ayo meji si odo ni Naijiria tun fi bori wọn.

November 22, 2008: Nigeria 1-0 South Africa

Oríṣun àwòrán, nff

Ọdún yii ni igba àkọ́kọ́ ti Naijiria ko gba ife ẹyẹ WAFCON.

Orile-ede Equatorial Guinea nì idije naa ti waye lọdun 2008.

 Ipo kẹta ni Naijiria ṣe. Àmọ́ ibẹrẹ pẹpẹ idije naa ni àwọn ati South Africa ti pade ni papa ìṣeré Estadio La Libertad, Bata. Ami ayo kan si odo ni wọn gbá.

November 4, 2010: Nigeria 2-1 South Africa

Oríṣun àwòrán, nff

Àgbò to tàdí mẹ́yìn, agbara lo lọ mu wa ni ọrọ Naijiria ni WAFCON 2010.

 South Africa wa lara awọn ti wọn fi iya jẹ, ti wọn tun fi rí ife ẹyẹ idije naa gba lẹẹkan si i.

 Wọn dáná ami ayo meji si ẹyọkan si wọn lara nilẹ baba wọn ni papa ìṣeré Sinaba Stadium.​

November 7, 2012: South Africa 1-0 Nigeria

Oríṣun àwòrán, nff

Fun igba àkọ́kọ́, ninu itan wafcon, South Africa fi ẹyin Naijiria janlẹ pẹlu ami kan si odo.

 Lílù ti Bayana Bayana naa wọn, ja wọn danu ṣáájú ki idije to wọ semi-final.

 Equatorial Guinea lo tun gba ife ẹyẹ fun igba keji lọdun naa.

October 22, 2014: Nigeria 2-1 South Africa

Ṣe ẹ o gbagbe pe South Africa lo ja Naijiria kuro ninu idije naa, pẹlu ami ayo kan si odo. Wọn o de ipele semi-final.

Ikanra ni Asisat Oshoala fi gbẹsan lara South Africa nigba ti wọn pade ni Windhoek, nigba ti wọn jọ pade.

Ipele aṣekagba idije naa ni wọn tun ti pade, lẹyin naa.

Ami ayo méjì si odo ni Naijiria fun wọn ni papa ìṣeré Sam Nujoma, ti wọn tun fi gba ife ẹyẹ.

November 29, 2016: Nigeria 1-0 South Africa

Wọn tun jọ pade ni ipele semi-final ni wafcon to waye ni Cameroon lọdun 2016.

Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa gbona pupọ, ṣùgbọ́n Naijiria pada bori pẹlu ami kan si odo nigba ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọ isẹju mẹrinlelaadọta.

November 18, 2018: South Africa 1-0 Nigeria

Oríṣun àwòrán, caf

Lọtẹ yii, àwọn agbabọọlu obìnrin South Africa ko ṣeré rara.

Àwọn pẹlu Naijiria lo jọ koju ara wọn ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́, nibi idije WAFCON to waye ni Ghana, Ghana 2018.

Ami ayo kan si odo ni South Africa fun Naijiria.

December 1, 2018: Nigeria 4-3 South Africa

Igbẹyin ni alayo n ta ni Super Falcons fi ọ̀rọ̀ ṣe nigba ti wọn jọ tun pade ni idije aṣekagba.  

Ọmi òdo ni wọn jọ kọ́kọ́ ta. Ṣugbọn Naijiria bori pẹlu ami mẹrin si mẹta nigba ti wọn gba pẹnariti.

Ọdún naa ni igba kẹsàn-án ti Naijiria gba ife ẹyẹ WAFCON.

 Taa ni yoo bori ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ ni Morocco?