Ẹ ṣọ́ra, Monkeypox tún lè dàbí àjàkálẹ̀ ààrùn bíi Coronavirus ní àgbáyé - WHO

Monkeypox: Ìpínlẹ̀ Eko lédé nínú àwọn ènìyàn 62 tó ti lùgbàdì Monkeypox ní Naijiria

Aworan Monkeypox

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun lorilẹede Naijiria ti fi lede pe eniyan mejilelọgta lo ti lugbadi arun naa lorilẹede Naijiria.

Ajọ NCDC fi eleyii lede ninu atẹjade nipa Monkeypox ti wọn fi sita ni Ọjọ Iṣẹgun.

Ajọ NCDC ni lati Osu Kini ọdun 2022 yii si Oṣu Kẹfa ọdun naa, ni wọn ti fi lede pe ipinlẹ mejidinlogun ni awọn eniyan ti ni arun naa ni Naijiria to fi mọ ilu Abuja.

Bakan naa ni atẹjade naa fi lede pe eniyan mẹrinlenigba ni afihan wa pe o ṣeeṣe ki wọn ti lugbadi aarun naa ni Naijiria.

Ọkunrin mẹrinlelogoji ati obinrin mejidinlogun lo ti lugbadi arun naa ni ilu mọkandinlogun.

Lara wọn ni eniyan mẹwaa ti lugbadi aarun naa ni ipinlẹ Eko, eniyan kan ni ipinlẹ Ọyọ, Ondo ati Ogun.

Awọn ipinlẹ to tun ni ni Adamawa (6), Bayelsa (5), Delta (5), Rivers (5), Cross River (4), Edo (4), FCT (4), Plateau (4), Nasarawa (3), Kano (2), Imo (2), Taraba (2), Abia (1), Katsina (1), Niger (1).

Bakan naa ni ẹni ogoji ọdun ti gbẹmi ni latari arun Monkeypox naa.

Ẹ ṣọ́ra, Monkeypox tún lè da àjàkálẹ̀ ààrùn bíi Coronavirus ní àgbáyé – WHO

Ajọ Eleto ilera lagbaye, WHO ti kilọ pe ti awọn orilẹede ko ba ṣọra, arun Monkeypox le dabi ajakalẹ arun Coronavirus lagbaye

Aṣoju wọn lorilẹede Naijiria, Dr. Walter Mulombo lo ṣọ bẹẹ nibi ipade pẹlu awọn akọroyin ti wọn pe akọle rẹ ni; “Monkeypox Spread, Infodemic & Public Health Response in Nigeria,”.

Dr. Walter Mulombo ni ti awọn orilẹede lagbaye ko ba ni abẹrẹ ajẹsara to gbooro lati koju aarun naa pe o sẹeṣẹ ko tankalẹ.

Bakan naa ni o fikun un pe abẹrẹ ajẹsara ti wọn fi n tọju ẹni to ni aarun Smallpox ti awọn orilẹede lagbaye nlo, eleyii ti ko wọpọ ni ilẹ Afrika.

Iwadii fihan pe o ṣeeṣe ko je awọn eku ni wọn n ṣe atakalẹ aarun naa ti ohun wa lati ara ẹranko si eniyan.