Wo ohun mẹrin tíjọba Ogun fẹ ṣe láti paná aáwọ̀ òṣìṣẹ́ àmọ́ tó forí ṣánpọ́n

Awọn ẹgbẹ osisẹ n se iwọde

Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe awọn oṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ Ogun ti da iṣẹ silẹ, iyanṣẹlodi alaini gbedeke si ni wọn bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.

Ẹwẹ, ohun ti awọn oṣiṣẹ n beere fun ni sisan awọn owo mọda-mọda alajẹsẹku tijọba yọ lara owo oṣu wọn fun oṣu mọkanlelogun.

Wọn tun n fẹ agbekalẹ ẹtọ owo ifẹhinti ti awọn oṣiṣẹ ati ijọba yoo dijọ ma a da owo si nibamu pẹlu ofin owo osu osisẹ tọdun 2006 to wa fun owo ifẹhinti nipinlẹ naa.

Bakan naa ni wọn tun n beere fun atungbeyẹwo ofin to wa fun owo ifẹhinti nipinlẹ Ogun.

Awọn osisẹ naa tun n rọ gomina lati san owo ajẹmọnu isinmi lẹnu iṣẹ (leave allowance) wọn.

Gbogbo eyi ni won n beere fun, ti wọn si lo digba ti gomina ba san gbogbo owo naa, ko to di pe awọn pada sẹnu iṣẹ wọn.

Ni kete ti wọn bẹrẹ iyanṣẹlodi naa, ni ijọba ti ranṣẹ pe awọn oloye ẹgbẹ osisẹ mẹfa lati ba wọn se ipade, awọn naa ni alaga ati akọwe ẹgbẹ NLC, TUC ati JNC.

Lẹyin ipade naa, ti wọn ṣe fun bi i wakati mẹsan ni ọfiisi gomina to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta, wọn ko pada fi ẹnu ọrọ naa ko sibi kankan.

Amọ gomina Dapo Abiodun rọ awọn osisẹ naa lati ṣe ọpọlọpọ suuru fun ijọba.

Wo ohun mẹrin tí ìjọba fẹ́ ṣe fáwọn òṣìṣẹ́:

Owo mọda-mọda ifẹhinti (Contributory Pension Scheme):

Ijọba loun yoo gbe igbimọ dide lati ṣe agbeyẹwo ilana owo ifẹyinti tuntun naa, ti igbimọ naa yoo si wa labẹ idari olori awọn oṣiṣẹ ijọba.

Amọ ẹgbẹ àwọn oṣiṣẹ ni oun ko fara mọ igbesẹ ijọba naa pe ki igbimọ naa wa labẹ idari ijọba

Owo ajẹmọnu isinmi lẹnu iṣẹ (Leave Allowance):

Gomina Abiọdun tun ni oun yoo paṣẹ pe ki kọmiṣanna fọrọ eto iṣuna ṣe agbeyẹwo sisan owo ajẹmọnu isismi fawọn osisẹ naa, lori bi wọn yoo ṣe maa san an loṣooṣu mọ owo oṣu awọn oṣiṣẹ.

Amọ ẹgbẹ oṣiṣẹ l'awọn ko faramọ ọn, ti wọn si ni awọn fẹ ki gomina san gbogbo owo naa lẹẹkan ṣoṣo loju ẹsẹ ni.

Sisan owo alajẹsẹku tijọba yọ lara owo oṣu wọn fun oṣu mọkanlelogun (21months cooperatives deductions)

Gomina Dapọ Abiọdun  wa jẹjẹ pe oun yoo san biliọnu kan ataabọ ninu biliọnu mejidinlaadọrin-le-diẹ (₦68.3b) to jẹ wọn ọhun.

Amọ ẹgbẹ osisẹ ni oṣu mẹta pere ni owo naa yoo ka amọ wọn la pe eyi to kere ju ti ijọba gbọdọ san ni oṣu mẹẹdogun.

 Igbega lẹnu iṣẹ:

Gomina loun fẹẹ bu ọwọ lu igbega fun ọdun 2021 si 2022, ṣugbọn ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ sọ pe awọn ko fara mọ ọn, bi ko ṣe pe ko bu ọwọ lu igbega fun awọn lati ọdun to ti kọja.

Lẹyin eyi ni ijọba gbe iwe adehun silẹ wi pe ki awọn olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ naa tọwọ bọ ọ, wi pe wọn ti fi ẹnu ko lee lori, ṣugbọn ti a gbọ pe wọn ko gba.

Iyanṣẹlodi ṣi n tẹsiwaju:

Kọmureedi Emmanuel Bankọle nibi ipade ti wọn ṣe ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Abiọla-Way, Lẹmẹ niluu Abẹokuta l'ọjọ Ẹti kede pe iyanṣẹlodi naa ṣi n tẹsiwaju.

O fikun pe awọn yoo tun korajọ l'ọjọ Aje, Mọnde lati ṣe ipade miran nipa igbesẹ to tun kan.

Òṣìṣẹ́ kan subú níbi ìfẹ̀hónú hàn l‘Ogun, ó kú pátápátá

Oríṣun àwòrán, , Comrade Olayemi Olusoji Olusegun

Iroyin to tẹ BBC Yoruba lọwọ ti f’idi rẹ mulẹ pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ ti wọn n ja fun ẹtọ wọn ti  ṣubu, to si ku patapata.

Isẹlẹ iku ojiji naa lo waye lasiko tawọn osisẹ n wosẹ niran lati fẹhonu han si ijọba ipinlẹ Ogun lori awọn ẹtọ wọn ti wọn n beere fun.

Kọmureedi Sunday Ogunjimi ni wọn pe orukọ oṣiṣẹ ijọba naa, ẹni ti wọn lo ti f’igba kan ri jẹ alaga ẹgbẹ awọn ọdọ lorileede Naijiria, ẹka ti Ọdẹda n’ipinlẹ naa.

Ọjọ Ẹti ana la gbọ pe Kọmureedi Sunday Ogunjimi jade laye lai duro dagbere f’awọn mọlẹbi rẹ wi pe o digboṣe.

Gbogbo bi wọn ṣe sọ pe wọn n rọ omi lee lori ni ko si ayipada kankan, eyi lo fa a ti awọn kan fi gba wọn lamọran lati gbe e lọ si ọsibitu Federal Medical Centre, FMC to wa ni Idi-Aba, Abẹokuta lati doola ẹmi.

Iyalẹnu lo jẹ pe ki wọn to gbe e debẹ, aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ, ẹlẹmin ti gba a, koda ti wọn l’awọn dọkita naa f’idi rẹ mulẹ pe ẹpa ko boro mọ.

Oríṣun àwòrán, Comrade Olayemi Olusegun

Olu ile ẹgbẹ osisẹ to wa ni Abiọla-Way, Lẹmẹ, niluu Abẹokuta, nibi tawọn osisẹ ipinlẹ Ogun peju si lasiko ti wọn n wosẹ niran ni isẹlẹ naa waye.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba,asaaju ẹgbẹ osisẹ kan, Comrade Olayemi Olusoji Olusegun, to jẹ alaga awọn osisẹ feto ilera ati isegun, ni nibi ti awọn oṣiṣẹ naa ti n fi ẹhonu wọn han s’awọn olori wọn, ti wọn lọ ba Gomina Dapọ Abiọdun ṣepade, ni ọkunrin naa ti ṣubu.

Ki oloju to o ṣẹ ẹ, wọn lawọn eeyan ti sare gbe e, ti wọn si rọ omi lee lori, lati le pada dide.

Gomina Dapọ Abiọdun: Mo setán láti báwọn òsisẹ́ tó dasẹ́ sílẹ̀ lójijì se ìpàdé báyìí

Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun loun ti ṣetan lati jokoo papọ ṣe ipade pọ pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa to da iṣẹ silẹ lojiji, ki wọn le jọ sọ asọyepọ.

Lonii, Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni agbarijọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ ọhun bẹrẹ iyanṣẹlodi, lẹyin ti ipade ti wọn ṣe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nibi ti wọn l’awọn ko ti i le sọ igba ati akoko ti wọn yoo pada s’ẹnu iṣẹ wọn.

Oríṣun àwòrán, Dapo Abiodun

Ọla, Ọjọru ti i ṣe Wẹside ni gomina sọ pe oun yoo ṣe ipade papọ pẹlu awọn oṣiṣẹ ọhun, to si loun ṣetan lati tẹti gbọ gbogbo ohun ti wọn n beere fun.

Ninu atẹjade ti kọmiṣọ́nna f’eto iroyin n’ipinlẹ Ogun, Alaaji Waheed Oduṣile fi sita lalẹ oni lo ti sọ pe gomina fẹẹ b’awọn oṣiṣẹ naa ṣe ipade papọ gẹgẹ bi ipinnu rẹ lati ri sọrọ igbayegbadun wọn.

“Mo ti mu gẹgẹ bi ojuṣe lati jẹ ki ọrọ awọn oṣiṣẹ n’ipnlẹ Ogun jẹ mi logun, ti mo si ṣetan lati maa fi si ojuṣe.

Ọrẹ awọn oṣiṣẹ ni iṣakoso yii jẹ, ti yoo si maa ri bẹẹ lọ labẹ iṣakoso mi.”.

“Ọkan lara awọn ojuṣe mi ti mo ṣe lọjọ akọkọ ti mo de ipo gomina l’ọgbọn ọjọ, oṣu karun-un, ọdun 2019 ni lati bu ọwọ lu owo oṣu gbogbo awọn oṣiṣẹ patapata, eyi ti iṣakoso to kọja ko tete san nigba naa. “Mo tun ṣe ileri wi pe gbogbo awọn oṣiṣẹ ni wọn maa gba owo oṣu wọn ko to o to tabi ni ipari oṣu. A si ti n ṣe bẹẹ latigba ti a ti bẹrẹ iṣẹ. “Koda, pẹlu bi ko ṣe si owo nilẹ to, ti bukata si n yọju ati iyanṣẹlodi yii, a tun ṣi san owo oṣu.

O da mi loju pe laaarin wakati mẹrinlelogun si asiko yii, wọn maa bẹrẹ si i ri owo oṣu wọn fun ti oṣu kẹfa yii.

A jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ lorileede yii ti wọn ko jẹ owo oṣu, ti a si n san an lasiko to yẹ”, Gomina Dapọ Abiọdun. Siwaju si i ni Gomina Abiọdun tun sọ pe ohunkohun ti awọn oṣiṣẹ le maa beere fun bayii, loun yoo tẹti gbọ,

ti wọn yoo si wa iyanju si, ati pe ọpọ ohun t’awọn oṣiṣẹ naa n beere fun lo jẹ labẹ iṣakoso to kọja lo ti wa,

ṣugbọn gẹgẹ bi ijọba to mọ ojuṣe rẹ, ẹyọkọọkan ti wọn n yọsẹ lawo lohun n ṣe e, koda lakoko ti ko si owo nilẹ yii.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Ogun bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì aláìní gbèdéke

Oríṣun àwòrán, Other

Ẹgbẹ́ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ogun, ti kesi awọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn, lati bẹ̀rẹ̀ iyanṣẹlodi alaini gbedeke.

Oru ọjọ́ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ni ireti wa pe iyanṣẹlodi naa yoo bẹ̀rẹ̀.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ pe oun fẹ lo igbeṣẹ naa lati beere fun eto irọrun lẹ́nu iṣẹ.

Nibi ipade ita gbangba ti awọn oṣiṣẹ naa ṣe ni gbagede to wa ni ọfiisi gomina, n'ilu Abeokuta, wọn ni iyanṣẹlodi naa jẹ igbeṣẹ to ṣe koko, nitori pe ọpọlọpọ ileri ni ìjọba ṣe fun àwọn, sugbọn ti ko mu ṣẹ.

Eyi n waye lẹyin gbedeke ọjọ́ ti ẹgbẹ́ oṣiṣẹ fun Gomina Dapo Abiodun, lori bi ko ṣe san awọn owo to yọ lara owo oṣu wọn fun oṣù mọkanlelogun.

Bakan naa ni wọn tun n fẹ́ eto owo ifẹhinti ti awọn oṣiṣẹ ati ijọba yoo jọ má a dá owo si, ni ibamu pẹlu ofin owo ọdun 2006 to wa fun owo ifẹhinti nipinlẹ naa, to fi mọ atungbeyẹwo ofin to wa fun owo ifẹhinti nipinlẹ Ogun.

Wọn ní o tun kọ lati san owo ajẹmọnu fun isinmi lẹnu isẹ (leave allowance).

Àwọn olori ẹgbẹ́ oṣiṣẹ lati Nigeria Labour Congress (NLC), Trade Union Congress (TUC), ati Joint Negotiating Committee (JNC) lo kede iyanṣẹlodi naa.

Iyanṣẹlodi yii yoo kan awọn ileeṣẹ ìjọba, ileewosan, ati awọn ile ẹ̀kọ́ to jẹ ti ìjọba.

Alaga ẹgbẹ́ oṣiṣẹ nipinlẹ naa, Emmanuel Bankole, sọ pe ọdalẹ ni ẹnikẹni to ba wa si ibi iṣẹ lẹyin ikede naa.