Ọmọ Naijria mẹ́wàá tó wà lókè téńté ‘Social Media Influencers’ rèé…

Social Media Influencers: Davido, Wizkid, Burna Boy wà lára àwọn mẹ́wàá tó làmìlaaka ní Twitter

Aworan Davido, Whizkid ati Burnaboy

Oríṣun àwòrán, other

Lilo oju opo ibaraẹni dọrẹ, Social Media lo gbode kan kaakiri agbaye bayii, ti ko si si agbegbe kan tabi omiran ti ẹrọ ayelujara ko si.

Amọ ninu awọn to wa lori ẹrọ ayelujara naa, awọn kan wa to jẹ pe ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan lo n tẹle wọn ‘followers’.

Ohun ti wọn ba sọ lori ẹrọ ayelujara ni abẹ ge to fi mọ ihuwasi wọn ni awọn eniyan n tẹle.

Lorilẹede Naijiria awọn mẹwaa to wa loke tente to jẹ bi awokọṣe lori ẹrọ ibaraẹnidọrẹ paapaa ni Twitter ni ọdun 2022 yii ni;

Davido (11.6 million followers)

David Adedeji Adeleke ti ọpọ eniyan mọ si Davido jẹ gbajugbaja olorin ti awọn ọdọ ni ilẹ Afirika fẹran.

Pẹlu iye awọn eniyan to n tẹle lori Twitter, eleyii ṣafihan bi awọn eniyan ṣe gba tirẹ paapaa orin rẹ fun awọn to gbadun orin taka sufe.

Wizkid (10.1 million followers)

Ilumọọka ni orukọ Wizkid laarin awọn olorin ni Naijiria ati awọn ololufẹ orin.

Orukọ abisọ rẹ ni Ayodeji Ibrahim Balogun, ti eniyan to le ni miliọnu mẹwaa n tẹle lẹyin Davido to fi miliọnu marun un ṣagba fun un.

Burna Boy (6.8 million followers)

Damini Ebunoluwa Ogulu, ti inagije rẹ n jẹ Burna Boy, lo jẹ olorin, to ma n kọrin lori itage,

Burna Boy ti gba Ami Ẹyẹ Grammy, eleyii to tun mu ki ọpọ eniyan tẹle ju titẹlẹ lọ lori ẹrọ ayelujara paapaa Twitter.

Don Jazzy (6.7 million followers)

Michael Collins Ajereh, ti ọpọ eniyan mọ si  Don Jazzy , ti ṣe gudugudu ni ẹka ere idaraya, amoju ẹrọ ati adẹrinpoṣonu.

Don Jazzy jẹ ọkan lara awọn to ni ileeṣẹ Mo’ Hits Records tẹlẹ pẹlu Dbanj. Bakan naa ni ọpọ  eniyan naa tun n tẹle lori Instagram.

DJ Cuppy (4.7 million followers)

Ọkan lara ọmọ Femi Otedola to jẹ baba olowo lorilẹede Naijiria, Florence Otedola ti wọn tun n pe ni DJ Cuppy, naa ni eniyan to le ni miliọnu mẹrin to n tẹle loju opo Twitter.

Iṣẹ  DJ ti awọn oloyinbo n pe ni disc jockey lo yan laayo, to si ti da ilumọọka ni idi rẹ.

Banky W (3.7 million followers)

Akọrin ati olorin to n gbe awo orin jade ni Bankole Wellington, ti ọpọ eniyan mọ si Banky W.

Ọpọ eniyan fẹran rẹ, to si tun ti ya si oṣelu bayii pẹlu bi o ṣe bori ninu eto idibo abẹle PDP lati dije du ipo aṣojuṣofin agbegbe Eti-Osa.

 

Falz (2.7 million followers)

Folarin Falana,ti orukọ ori itage rẹ n jẹ Falz,jẹ olorin takasufẹ ti ọpọ eniyan fẹran.

Bkan naa lo jẹ ajafẹtọ ọmọ eniyan paapaa ni Naijiria.

Bio tilẹ jẹpe iṣẹ agbẹjọro lo lọ kọ ni ileẹkọ, amọ iṣẹ orin lo yan laayo.

Ebuka (2.5 million)

Sọrọsọrọ agbohunsafẹfẹ ni Ebuka Obi-Uchendu, ni ọpọ mọ si Ebuka lori ẹrọ ayelujara.

Ebuka lo ma n ṣe atọkun eto ero tẹlifisọn ni ọdọọdun,BBNaija.

Mr Macaroni (2.4 million followers)

Debo Adedayo, ni ọpọ mọ si Mr Macaroni, jẹ adẹrinposonu ati ajafẹtọ ọmọniyan ni Naijiria.

Adẹrinpoṣonu bii baba agbaya ti kii jẹ ki awọn obinrin sinmi lo ma n ṣe ninu ere rẹ, ti wọn n pe ni “sugar daddy”.

Ay Comedian (2.1 million followers)

Ayodeji Richard Makun, ni ọpọ mọ si A.Y, adẹrinposonu, oṣere, sọrọsọrọ, onkọwe ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Funke Akindele (1.7 million followers)

Olufunke Akindele-Bello ni ọpọ mọ si Funke Akindele or Jenifa jẹ gbajugbaja oṣere ni Naijiria.

O kopa ninu fiimu agbelewo ‘I Need to Know’ lati ọdun1998 si 2002, to si ti gbe ọpọlọpọ fiimu jade lati igba naa to fi mọ Jenifa ati Jenifa’s Diary.

Ọdun 2009 lo gba Ami Ẹyẹ oṣerebinrin to lamilaaka julọ ninu ere.