Àjọ bọ́ọ̀lù Sierra Leone yóò wádìí Àràmàǹdà ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ líìgì níbi tí àwọn agbábọ́ọ̀lù ti gbá góòlù 91-1 àti 95-0 wọlé

ife ẹyẹ liigi ilẹ Sierra Leone

Oríṣun àwòrán, sierra leone football association

Ajọ elere bọọlu lorilẹede Sierra leone ti gbe iwadi kalẹ lori ifẹsẹwọnsẹ bọọlu meji kan to waye ni liigi ilẹ naa.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji to bori ninu ifẹsẹwọnsẹ naa n lepa ati ni agbega si liigi to ga julọ lorilẹede naa.

Ajọ ere bọọlu lorilẹede naa ni oun yoo ṣe iwadii awọn alamojuto ifẹsẹwọnsẹ naa atawọn agbabọọlu to kopa pẹlu.

Ami kan naa lawọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji wa, ifẹsẹwọnsẹ to jẹ aṣekagba saa bọọlu naa awọn ikọ mejeeji yii nlepa ẹni ti iye goolu rẹ yoo pọju ni.

Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ mejeeji yoo si fi pari, ẹgbẹ agbabọọlu Gulf FC na Koquima Lebanon ni goolu mọkanlelaadọrun si ẹyọkan, 91-1

Bakan naa ni Lumbenbu United si jiya goolu marundinlaọgọrun si odo, 95-0 lọwọ Kahula Rangers

Oríṣun àwòrán, Ajọ bọọlu orilẹede Sierra Leone

Fọran fidio lati ibudo ifẹsẹwọnsẹ tio waye ni Kenema city fihan bi awọn agbabọọlu ṣe n mọọmọ gba bọọlu fun awọn agbabọọlu alatako lati gba bọọlu sinu awọn.

Fun pẹnariti to waye, nṣe ni aṣọle fo lọ si ọna to yatọ gedegbe si ibi ti bọọlu lọ, to si lulẹ bii apo ẹwa nibẹ.

Ajọ ere bọọlu lorilẹede Sierra Leone ti sọ pe ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori pe o ṣe idunadura nipasẹ ifẹsẹwọnsẹ naa  yoo ba ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede naa lalejo fun igbesẹ to ba yẹ.