Èmi kò ní pé kí ẹ lọ ra ìbon o- Pásítọ̀ Adeboye

Pásítọ̀ Adeboye

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ṣáájú ni Pásítọ̀ Enoch adejare Adeboye to ń tuko ìjọ ìràpadà the redeemed Christian Church of God tí sọ̀rọ̀ lórí eto ààbò àwọn Kristẹni nínú ìjọ won

Lásìkò ìsò òru olosoosu ìjọ RCCG to wáyé ní orumoju ojo Àbámẹ́ta yìí ló ti sọ ọrọ naa

Pásítọ̀ Adeboye ni ohun ibanuje ni bí àwọn onise ibi kan ṣe n kọlu àwọn olùjọsìn Kristẹni nínú ilé ìjọsìn wọn to ń ṣẹlẹ̀ ní àsìkò yii

Lẹ́yìn náà lọ sọ pé kí onikaluku lọ máa pèsè ààbò to yẹ láti gbéjà ara rẹ lòdì sí ìkọlù àwọn onise ibi tó ń wọ́pọ̀ síi lásìkò yii

Adeboye tún kìlọ̀ pé kò yẹ kí àwọn èèyàn máa sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run láìní fi ṣe ẹṣin kankan

O menuba ìfẹ́ àti ìfaradà tó ń fáàyè gba àlàáfíà laarin awọn èèyàn láìní fi ṣe irú ìran, aawo ara wọn, eya tàbí ẹṣin tí wọ́n ń sin

O ni asiko ti tó láti fòpin sí ìkọlù sílè ìjọsìn kankan lásìkò ìjọsìn tó ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà báyìí

Lẹ́yìn ìwàásù Adeboye yìí ni àwọn ọmọ Nàìjíríà ń fi èrò wọn hàn lórí ayélujára lórí koko ìpèsè ààbò nílé ìjọsìn lásìkò yii

Ṣùgbọ́n ní owuro òní, ọjọ́ isinmi, ọjọ́ kẹta oṣù keje ni Adeboye tún ṣàlàyé síi lórí koko eto ààbò nílé ìjọsìn to koko sọ̀rọ̀ lè lórí ni Redemption camb lọ́jọ́ Ẹtì

Adeboye ni pé kó di ìgbà tí èèyàn bá gbé ìbon kò tó pèsè ààbò fún ara rẹ rara

Lásìkò to ń wàásù níbi ìsìn ọpẹ olosoosu Nike ìjọsìn RCCG to wá ní èbúté metta lọ tí sọ̀rọ̀ ni kíkún lórí lílọ ìbon fi pèsè ààbò naa

Adeboye fi ìtàn Samsoni alágbára inú Bíbélì ṣe àkàwé nígbà tó fi párì ẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gba ara rẹ lọ́wọ́ ota

O ni òun kò ní pé kí àwọn Kristẹni lọ ra ìbon bikose pé kí wọ́n lọ ohun tí Bíbélì sọ fi dáàbò bo ara won

Bákan náà lọ gbàdúrà pé kí Olódùmarè dá sí ọ̀rọ̀ ipenija to ń koju eto ààbò olùgbé Naijiria lásìkò yii

O tún ro awon ọdọ láti má ṣe ọ̀le ṣùgbọ́n kí gbogbo osise tepa mo ìṣe owó wọn fún ìgbéga.

O gba àwọn ọmọ Nàìjíríà ni ìmọ̀ràn láti bù owó fún Olódùmarè kí wọn sì gba òdodo àti ìfẹ́ láàyè