A ti gbáradì fún ikọ̀ Super Falcons – Banyana Banyana ti South Africa

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Ikọ agbabọọlu obinrin ti orilẹede South-Africa ti fi ero wọn ha ni igbaradi fun idije CAF Women Cup of Nations ti yoo waye ni Morocco.

Ikọ Super Falcons to ti gba ami ẹyẹ naa fun igba kẹsan ti yoo ma koju ikọ Banyana Banyana ni ifẹṣẹwọnṣẹ group C ti yoo waye ni Ọjọ Kẹrin, Osu Keje.

Dokita Iko Banyana Banyana, Rodney Mokoka naa lo ni awọn ti rẹkẹ ikọ agbabọọlu obinrin ti Naijiria ati awọn ikọ agbabọọlu to ku.

Ninu fidio ti Mokoka fi lede lo ti safihan bi awọn ikọ South Africa naa ṣe n gbaradi.

Bakan naa lo ni awọn ti ṣetan lati kopa ninu idije ikejila ti Women’s Africa Cup of Nations ni Morocco.

Dokita naa ni ara wọn pe sasa ti ko si si ẹni to ni aisan kankan lara awọn obinrin agbabọọlu naa.