Nigeria: Ọwọ tẹ afurasi mẹrin lori iku ọga SARS

Awọn ọlọpa ton gbogun tawọn adigunjale Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ileesẹ ọlọọpa Naijiria ko sinmi lati gbogun tiwa ọdaran

Olu ilese ọlọpa nipinle Ọyọ ti sọpe ọwọ ti te afurasi merin ninu awọn eeyan to sekupa Seu Magu, ọga ọlọpa SARS, to n gbogun tawọn adigunjale, ti wọn pa ni ijeta.

Agbẹnusọ fun ileese ọlọpa nipinle Ọyọ, Adekunle Ajisebutu, sọ wipe awọn adigunjale ni wọn pa ọga ọlọpa SARS naa.

Iroyin ti kọkọ gbale kan wipe awọn darandaran ni wọn pa ọlọpa naa.

Sugbọn nigba to n ba akọroyin ileesẹ BBC sọrọ, Ọgbeni Ajisebutu ni, ẹnikẹni to ba gbẹmi eeyan, ọdaran ni, pẹlu afikun pe ọdaran nikan lo lee se iku pa ọlọpa to ngbogun tawọn adigunjale.

Ajisebutu so wipe iwadi nlọ lọwọ-lọwọ nipa iku ọga ọlọpa naa.

O sọ wipe ni kete ti wọn ba ti pari iwadi wọn naa, lawọn afurasi ti ọlọpa mu, yoo fi oju ba ile ẹjọ.