Àwọn ọ̀nà tí obìnrin fi le gbádùn ìbálòpọ̀

woman and man dey have sex Image copyright Laurene Boglio

Onimọ kan nipa ibaṣepọ ọkunrin ati obinrin ti jẹ ko di mímọ̀ pé oriṣiriṣi ọna ni obinrin fi le gba ìtura lasiko ibalopọ̀.

Audrey Andrews sọ fun iwe iroyin Daily Mail UK oriṣiriṣi ọna ti awọn obinrin fi le mọ pe awọn ti gba itura lasiko ibalopọ.

1. Itura orí idọ ojú ara (Clitoral Orgasm)

Eyi lo wọpọ ju, to si jẹ pe ìdá ààdọ́run ninu awọn obinrin ni yoo ni iriri yii lasiko ti wọn ba fi ọwọ tabi nkan ọkunrin kan idọ̀ oju ara ara wọn,

Iṣẹ́ kan ti idọ̀ n ṣe ni pe ko fun obinrin ni adùn ibalopọ.

2. Ìtura lati oju ara tabi G-Spot

G-spot ni orukọ ti wọn n pe aaye kekere kan to wa ni oke tente iwaju oju ara obinrin, eyi si le fun awọn obinrin ni itura ti wọn ba fi ọwọ́ tabi nkan ọkunrin rìn wọ́n níbẹ̀.

Image copyright Laurene Boglio

3. Ìtura alápapọ̀ (Blended Orgasm)

Obinrin le gba iru itura yii ti ọkunrin ba fi ọwọ kàn ju ẹya ara rẹ̀ kan lọ lẹ́ẹ̀kan naa.

Eyi le waye lasiko ti obinrin ba n ni ibalopọ tabi ti wọn ba n fi ọwọ́ pá à lara.

4. Ìtura ọ̀pọ̀ yanturu (Multiple Orgasms)

Eyi ni pe ti o ba gba itura kan, ti o sinmi diẹ, ti o tun gba itura mi lera-lera lai dawọ duro.

Ti o ba fẹ gba itura ju ẹẹkan lọ, sinmi fun bi iṣẹju kan tabi meji ki o to pada gba ikeji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionG-string tàbí Hip-star, èwo lo fẹ́ràn jù?

5. Ìtura ihò ilé ìgbẹ́ (Anal Orgasm)

Ọpọlọpọ obinrin le gba itura ti wọn ba ni ibalopọ lati iho ile ìgbẹ́, bi o tilẹ jẹ pe ko wọ́pọ̀.

6. Ìtura ojó oorun (Sleep-Gasm)

Nitori pe ọpọlọ eniyan ni agbára, o tumọ si pe awọn obinrin tun le ni itura ibalopọ l'oju oorun wọn.

Ara rẹ maa n sinmi lasiko ti o ba n sùn, ko si pe oun ronu ohunkohun, ọkan rẹ si le ronu oriṣiriṣi nipa ibalopọ.

Iru awọn ironu yii le mu ọ ni itura lati oju oorun rẹ, o si le ji ọ pada s'áyé.

Image copyright Getty Images

7. Ìtura ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ (Cervical Orgasm)

Eyi jẹ ọkan lara àwọn ọ̀nà pataki ti obinrin fi maa n gba itura lasiko ibalopọ, paapa ti nkan ọmọkunrin ba wọ inu oju ara daada.

8. Ìtura lati ibi ti ìtọ̀ n gba jade (U-Spot Orgasm)

Ibi ti itọ n gba jade ki i ṣe fun ìtọ̀ nikan, nitori pe awọn ẹ̀yà kan lara idọ̀ wa lara rẹ, eyi to maa n fun obinrin ni itura ti wọ́n ba fi nkan rìn ín.

Image copyright Getty Images

10. Ìtura lati orí ọmú (Nipple Orgasm)

Fifi ọmú ati orí ọmú ṣere maa n mu ki ọpọlọ jí, to si maa n mu ki idọ gbá yágí-yágí, paapa ti wọn ba mu u. O maa n ji èròjà ara ti wọn n pe ni Oxytocin, ti i ṣe homoonu ìfẹ́.