Scientific Reports: Ìgbẹ́ ọmọdé ní àǹfààní púpọ̀ lára

Igbẹ ọmọde Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn dokita lati ilẹ Amẹrika naa fikun wipe o seese ki igbẹ ọmọde jẹ ọna abayọ si gbogbo aarun ti n pa awọn eniyan lai to ọjọ.

Imọ tuntun ti fihan wipe igbẹ ọmọde le koju awọn aarun bii jẹjẹrẹ, sisanra l'asanju, aisan ìtọ̀ suga ati awọn aisan ẹjẹ miran.

Iwadii ti awọn dokita onimọ lati ilẹ Amẹrika fi sita ninu akojọpọ iwe Scientific Reports fihan wipe kokoro aifojuri kan wa ninu igbẹ awọn ọmọde ti o le pese eroja ara kan ti wọn n pe ni 'probiotic' ti wọn nilo lati koju aisan sisanra ju ati arun jẹjẹrẹ.

Ti eroja asaraloore probiotics ti wọn n fi si inu awọn ounjẹ ipapanu bii yogọọti gẹgẹbi eroja asaraloore ba wa ni ara eniyan, yoo seese fun ounjẹ lati da ni inu eniyan fun sise ara loore.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ògidì ọmọ Yorùbá ni mí, kò sí ọ̀rọ̀ tí n kò lè túmọ̀'

Awọn dokita lati ilẹ Amẹrika naa fikun wipe o seese ki igbẹ ọmọde jẹ ọna abayọ si gbogbo aarun ti n pa awọn eniyan lai to ọjọ.

'Fífún ọkọ àti ọmọ l'ọ́yàn ń dènà jẹjẹrẹ ọyàn'

O ti pẹ ti ariyanjiyan ti wa lori ẹni to ni ọyan aya obinrin laarin ọkọ rẹ ati ọmọ wọn.

Image copyright Getty Images

Diẹ lara awọn ọkunrin to ba BBC Yoruba sọrọ ninu fidio isalẹ yii ni ọkọ lo ni ọyan aya obinrin, pe ọmọ ti wọn bi kan ya a lo fun igba diẹ ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn ọkùnrin sọ èrò wọn lórí àríyànjiyàn ẹni tó ni ọyàn obìnrin láàrin bàbá àti ọmọ.

Ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ si ọjọ keje ni wọn ya sọtọ lati polongo pe ki awọn obinrin maa fun awọn ọmọ wọn lọyan, o kere tan, oṣu mẹfa.

Lẹyin eyi ni wọn to le fun iru ọmọ bẹẹ ni awọn ounjẹ aṣaraloore miran.

Ajọ to n mojuto eto ilera l'agbaye, WHO, to fi mọ UNICEF, ni omi ọyan ni awọn eroja aṣaraloore fun awọn ọmọde.

Onimọ nipa eto ilera, Abilekọ Grace Oluwatoye, sọ fun BBC Yoruba pe 'o yẹ ki obinrin fun ọmọ ni ọyan fun oṣu mẹfa akọkọ ti wọn ba bi'.

Omi ọyan to kọkọ jade lara ọyan fun ọjọ mẹta akọkọ lẹyin ti iya ba bi mọ tan dara pupọ, nitori pe awọn eroja to wa ninu rẹ dara fun ilera ọmọ tuntun.'

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn obìnrin kan tilẹ̀ máà n ta omi ọyàn wọn fún àwọn ìyálọ́mọ́ tí kò le fún àwọn ọmọ wọn ní ọyàn

O ni eyi yoo ṣe iranlọwọ fun idagbasoke ati ọjọ iwaju awọn ọmọ naa, ati pe fi fun ọmọ lọyan maa n mu ki ifẹ ati isopọ wa laarin iya ati ọmọ.

Bakan naa lo rọ ijọba ati awọn agbanisiṣẹ lati ṣe awọn alakalẹ eto ninu eto isejọba ti yoo fun awọn obinrin ni anfaani lati fun awọn ọmọ wọn ni ọyan nikan ṣoṣo fun oṣu mẹfa akọkọ lai ni abula.

Kin ni awọn onímọ̀ sọ lórí ki ọkunrin maa mu ọyan iyalọmọ?

Abilekọ Oluwatoye ni ko si oun to buru ninu ki ọkọ mu ọyan aya iyawo rẹ lasiko to ba n t'ọmọ lọwọ, nitori ko si ewu kankan fun ọkunrin bẹẹ.

O fi kun un pe eyi yoo tun mu ki ifẹ to wa laarin ọkọ ati aya l'agbara sii.

Ati pe iwadi fihan pe aisan jẹjẹrẹ yoo jina si obinrin to ba n fun ọmọ ati ọkọ rẹ l'ọyan.

O ni koda, omi ọyan obinrin dara ju ti ẹranko lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSunday Ayẹni: Damilọla, aya ọmọ mi fìgbónára sọ mi sókùnkùn alẹ́