Bí akọni ni wọ́n kí Arsène Wenger káàbọ̀ sí orílẹ̀èdè Liberia

Mọlẹbi kan to jẹ́ olúlùfẹ́ Arsenal n ya fọ́tò lásìkò tí Wenger gúnlẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú ní ìlú Harbel, Liberia Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Mọlẹbi kan to jẹ́ olúlùfẹ́ Arsenal n ya fọ́tò lásìkò tí Wenger gúnlẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú ní ìlú Harbel, Liberia

Ogúnlọ́gọ̀ àwọn ololufẹ ẹgbẹ́ agbabọọlu Arsenal tu jade lati ki Arsène Wenger kaabọ si Liberia, fun eto fifi ami ẹ̀yẹ danilọla, nibi ti oun naa yoo ti gba ami ẹ̀yẹ to ga julọ ni orilẹede naa.

Olukọni nigba kan fun Arsenal ọhun, ni akọnimọọgba akọkọ ti Aarẹ George Weah ni gẹgẹ bi agbabọlu nilẹ Yuroopu, oun naa lo si mu wọ inu ẹgbẹ́ agbabọọlu Monaco l'ọdun 1988.

Aarẹ Weah ṣe asẹyọri titi to fi di ọmọ ilẹ Afrika kan ṣoṣo to gba ami ẹyẹ agbabọọlu to dara ju l'agbaye lati ọwọ ajọ Fifa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOkodoro ọrọ meje nipa George Weah

Wọn yoo gba Wenger wọle sinu akọsilẹ ami ẹ̀yẹ fun awọn akọni orilẹede Liberia, ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ.

Wọn yoo si fun ni ami ẹ̀yẹ Knight Grand Commander of the Humane Order of African Redemption.

Image copyright EPA
Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Idunnu ni àwọn ololufẹ Arsenal l'orilẹede Liberia fi ki Wenger kaabọ si orilẹede wọn

Papakọ ofurufu agbaye to wa ni Harbel, ti ko ju kilomita mejilelaadọta si olu-ilu Liberia, Moronvia, ni minisita fun ọrọ awọn ọ̀dọ́ ati ere idaraya, Zoegar Wilson (oun lo wa ni apa ọtun) ninu aworan isalẹ yii, ti ki i kaabọ.

Image copyright EPA
Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Arsène Wenger ba awọn ololufẹ Arsenal ya fọ́tò ni papakọ ofurufu

Wenger sọ fun awọn akọroyin pe oun wa lati ki Aarẹ Geroge Weah ni, pe oun ko mọ nipa ami ẹyẹ naa.

Ṣaaju asiko yii lo ti sọ pe ori oun wú nipa Aarẹ Weah ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC.

O ni ''mo ranti igba akọkọ ti mo ri i ni Monaco, to wọle bi ẹni ti ko mọ ibi to n lọ, nitori pe ko mọ ẹnikẹni ri nibẹ, ti ko si si ẹnikẹni to ka a si gẹgẹ bi agbabọọlu, to fi di asiko to gba ami ẹyẹ agbabọlu to dara julọ ni agbaye l'ọdun 1995, ati igba to di aarẹ orilẹede rẹ.''

"Igbeaye ọmọkunrin yii da bi fiimu. O ṣoro lati gbagbọ. Fiimu ti yoo ta daada ni.''

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Ololufẹ Arsenal kan gbe akọle kan dani lati ki Wenger kaabọ ni papakọ ofurufu to gunlẹ si

Ṣugbọn, ki i ṣe gbogbo eniyan ninu wọn dun si dídé rẹ

Akọroyin BBC to wa ni Moronvia, Jonathan Paye-Layleh, jábọ̀ pe awọn ọmọ orilede Liberia kan sọ pe ko yẹ ki wọn fun ẹnikẹni ni ami ẹ̀yẹ naa nitori oore ti wọn ṣe aarẹ.

Awọn kan tilẹ sọ pe ''awọn akọnimọọgba to kọ Weah níṣẹ́ ko to di agbabọọlu agbaye lo yẹ ko fi ami ẹ̀yẹ naa da l'ọla.

Ojúdé Ọba 2018: Asọ ń pe asọ ránsẹ́

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIlu Ubang, jẹ ilu kan nibiti ede ti awọn ọkunrin wọn n sọ yatọ si ti awọn obinrin wọn.

Minisita fun eto iroyin l'orilẹede Liberia, Eugene Nagbe, sọ fun BBC pe, ami ẹyẹ naa ki i ṣe nitori ibaṣepọ ti Weah ni pẹlu Wenger nikan, bi ko ṣe ọ̀nà lati fi ẹmi imoore han si ọmọ orilẹede France ọhun, fun ipa to ko ninu ere idaraya ni ilẹ Afrika, ati anfaani to fun ọpọlọpọ ọmọ Afrika.

Agbabọọlu mẹrindinlogun to jẹ ọmọ ilẹ Afrika, ninu eyi ti ati ri Kolo Toure, to jẹ ọmọ orilẹede Ivory Coast, ati Kanu Nwankwo, to jẹ ọmọ̀ Naijiria ni Arsène Wenger kọ ni bọọlu gbígbá.

Related Topics