Ohun tí ó yé kóò kọ́ nípa ìròyìn òfégè ṣáájú ìdìbò 2019

fake news illustration
Àkọlé àwòrán Iroyin òfegè máa n ṣakoba fawọn ara ìlú ni

Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kìí ronú jinlẹ̀ kí wọ́n tó máà pín ìròyìn lórí ayélujára.

Èyí ni ohun ti ìwádìí ìjìnlẹ̀ BBC kan tí wọ́n pè ní 'Beyond Fake News' fìdí rẹ̀ múlẹ̀. Títàn káàkiri ìròyìn òfégè máá ń t'àbùkù bá ojúlówó ìròyìn.

Ìwádìí BBC náà ṣe agbéyẹ̀wò àwọn àtẹ̀ránṣẹ́ orí WhatsApp àti Facebook láàrin àwọn ọmọ orílẹ̀è-dè Naijiria, Kenya àti India, tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sì fìdí tí àwọn ènìyan fi máa ń pín ìròyìn òfégè káàkiri múlẹ̀.

Ìwádìí náà ran ni lọ́wọ́ lati mọ̀ àṣepọ̀ tó wà láàrin ìròyìn òfégè àti òṣèlu lórí ayélujára.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionParental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionO tó ìdá méjì àwọn ènìyàn àgbáyé to wà nínú ewu àìsàn ibà

Kíni ìròyìn òfégè ṣe ṣe pàtàkì?

  • Ó máa ń ba ìgbẹ́kẹ̀lé jẹ́
  • Ó máa ń mú ipínyà gbèèrú si
  • Ó máa ń tàbùkù bá òtítọ́
  • Àwọn ojúlówó ilé ìròyìn ló ń jíyà rẹ̀
  • Ó máá ń jẹ́ kí ó nira fún àwọn ará ìlú láti ṣe ìpinnu lóri ìgbésẹ̀
  • Kò dára fún ìrọ̀rọ̀wérọ̀
  • Kò tilẹ̀ dára fún àlàáfíà ará ìlú
  • Ó máa ń fa ọ̀rọ̀ ìkóríra, ìwà ìpá àti ikú
  • Ó máa ń ba íjọọba tiwantiwa jẹ́
  • Ó sì máa ń sọ ìròyìn di irinṣẹ́ ogun

Àwọn ìròyìn míràn ti ẹ lè nifẹ si:

Kílódé tí awọn ènìyan maa ń gba ìròyìn òfégè gbọ́?

BBC ṣe akíyèsí nínú ọ̀rọ̀ àwọn tí ó ń lo ojú òpó ìkànsíraẹni ní Naijiria àti Keyan pé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ni kò mọ̀ bí wọ́n ṣe máa ń dá ìròyìn òfégè mọ̀.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pe wọ́n mọ̀ ewu tó wà níní pínpín ìròyìn òfégè, kò yé wọ́n tó pe ìròyìn òfégè lè dojú ìjọba tiwantiwa bolẹ̀ tó sì lè ran àwọn olóṣèlú lọ́wọ́ láti yí ìbò.

Tí ètò ìdìbò bá ti n bọ̀ lọ́nà, ayédèrú ìròyìn ṣábà máà n wọ́pọ̀. Tí igun òṣèlú kọ̀ọ́kan sì máà n gbìyànjú láti ta ara wọn yọ.

Ṣùgbọ́n pé o mọ̀ pé ayédèrú ìròyìn wà, kò túmọ̀ sí pé o le daa mọ̀ tí o bá ri i.

Onímọ̀ kan ní fásitì Open University l'órílẹ̀-èdè Amẹrika, Ọ̀mọ̀wé Philip Seargeant, sọ pé ''ohun gbogbo ni àdínkù maa n dé bá pàtàkì rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára.''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'A máa ń bẹ́ orí ẹni tó bá gbé imọlẹ̀ ọdún ìjẹṣu tó bá ṣubú ni'

"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ọ̀rọ̀ tó l'ágbára maa n di yẹ̀yẹ́ lórí ayélujára."

"Ó sì ṣáábà máà n ní ọwọ́ òṣèlú nínú.

Pẹ̀lú bí ètò ìdìbò ọdún 2019 ṣe n kanlẹ̀kùn l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn ìròyìn kan ti jáde tó jẹ́ ayédèrú.

Lára wọn ni ìròyìn kan tó sọ pé Àlámòjútó ìjọ Ìràpadà Krístì (RCCG), Enoch Adeboye, bẹ adarí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Bọla Tinubu, láti fàáyè gba gómínà ìpínlẹ̀ Eko, Akinwumi Ambọde láti dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kan si i.

Ṣùgbọ́n, ìjọ RCCG ní irọ́ pátápáta ni ìròyìn nàá tí ìwé ìròyìn New Telegraph gbé síta.

Òmíràn tún ni ìròyìn kan tí gbajúgbajà akọ̀ròyìn, Dele Mọmọdu gbé jáde pé àjọ EFCC gbẹ́sẹ̀ lé àsùnwọ̀n gbajúgbajà olórin, David Adeleke (Davido) àti gbogbo ẹbí Adeleke nítórí pé ọ̀kan lára wọn, Ademọla Adeleke n dupò gómìnà l'Ọṣun.

Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ ni Mọmọdu padà tọrọ àforíjì pé irọ́ ni ìròyìn tí òun gbé jáde.

Ṣùgbọ́n, báwo ni o ṣe le dá ayédèrù ìròyìn mọ̀? Ọ̀mọ̀wé Philip Seargeant ti fásitì Open University l'órílẹ̀-èdè Amẹrika pèsè àwọn ọ̀nà àbáyọ kan.

1 - Ṣe àyẹ̀wò orísun ìròyìn nàá

Nkan àkọ́kọ́ tó sẹ pàtàkì ni láti yẹ orísun tí ìròyìn nàá ti wá wò, láti mọ̀ bóyá èyí tó ṣe é f'ọkàn tán ni.

Èyí le túmọ̀ sí pé o mọ ìtàkùn àgbáyé(website) tí o fẹ́ yẹ̀ wò. Nítorí ìdí èyí, yẹ àdírẹ́sì (URL) nàá wò.

Kò burú tí o bá ṣiyèméjì bóyá ìléèṣẹ́ ìròyìn tí o kò gbọ́ nípa rẹ̀ rí lógbé ìròyìn nàá jáde.

2 - Ṣé ìtàkùn àgbáyé kan ṣoṣo ló gbé ìròyìn nàá jáde?

Ohun tó kàn ni láti mọ̀ bóyá iléèṣẹ́ ìròyìn míràn gbé e síta lórí ìtàkùn àgbáyé wọn.

O le ṣe àmúlò Google láti fi wò ó bóyá ìṣẹ̀lẹ̀ nàá kò tilẹ̀ wáyé.

Àwọn ìtàkùn àgbáyé bi i Snopes tàbí factcheck.org le ràn án ọ́ lọ́wọ́, bákan nàá ni ti BBC Reality Check .

Tó bá jẹ́ pé orísun kan nàá ni gbogbo ìwádìí rẹ̀ n tọ́ka sí, a jẹ́ wí pé ó ṣeéṣe kó ní bayo-báyó nínú.

''Ṣùgbọ́n tí o bá ri i pé iléèṣẹ́ ìròyìn bi i méjì sí mẹ́ta ló gbé ìròyìn nàá, ó le finilọ́kàn balẹ̀ díẹ̀.

3 - Kíni àfojúsùn iléèṣẹ́ ìròyìn nàá?

''Gbogbo iléèṣẹ́ ìròyìn ló ní àfojúsùn. Àwọn àfojúsùn bẹ̀ ẹ́ sì maa n mú ègbè dání nígbà míràn, pàápàá àwọn ayédèrú ìtàkùn àgbáyé maa n ní àfojúsùn tí wọ́n n lépa.

Mí mọ èròngbà tàbí ohun tó n ṣe ìwúrí fún ẹni tó gbé ìròyìn nàá jáde le ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pinnu bóyá ayédèrú tàbí òtítọ́ ni ìròyìn nàá.

4 - Má à dúró lórí àkọlé ìròyìn nìkan

Wọ́n maa n gbé àwọn ayédèrú ìròyìn kan jáde láti fi pa àwọn ènìyàn lẹ́ẹ̀rín. Nítorí nàá, kà á dáàda láti mọ̀ bóyá wọ́n kàn fẹ́ ẹ́ fi gbọ́ tẹnu rẹ ni.

5 - 'Àwọn iléèṣẹ́ ìròyìn nlá kò ní ì gbé irú ìròyìn bẹ̀ ẹ́

Àwọn ènìyàn kan an gbàgbọ́ pé àwọn iléèṣẹ́ ìròyìn nlá maá n ṣègbè.

Èyí sì maa n mú kí wọ́n fi ara mọ́ àwọn kan tí wọ́n gbàgbọ́ pé 'kìí ṣègbè.'

Àti pé tí àwọn iléèṣẹ́ ìròyìn nla kò bá jábọ̀ ìrìyìn nàá, ó gbọdọ̀ wà ní ojú òpó mì í.

6 - Orísun àkọsílẹ̀

Ri i dájú pé o mọ ibi tí wọ́n ti rí àwọn ònkà tí wọ́n fi sínú ìròyìn nàá.

O le fi ọkàn tan an tó bá jẹ́ àábọ̀ ìwádìí àjọ nla kan ni wan múlò.

" O gbọdọ̀ siyè méjì tí o kò bá tí ì gbọ́ nípa orísun nàá rí tàbí bóyá ó ní ìlépa kan.

#beyond fake news