Rape: Ọmọ tí wọn ń fipá bá lòpọ̀ yóò máa ní ìrora ọkàn nígbà gbogbo

Aworan ọmọde ti wọn ba lopọ Image copyright Getty Images

Lojoojumọ ni iroyin ifipa ba ọmọde lopọ lorilẹede Naijiria ati kaakiri agbaye n peleke si, eyi to ti di irawọ ọsan, to n ba awọn agba lẹru bayii.

Nigba miran paapa, o le jẹ ẹgbọn, alabagbele, ara adugbo tabi baba ọmọdebinrin naa, lo fi ipa ba a lopọ.

Nigba miran ẹwẹ, awọn obi ọmọdebinrin ti wọn ba lopọ kii tete mọ nipa isẹlẹ ifipabanilopọ naa, ti yoo si maa waye ni igba gbogbo. Omiran tilẹ ti maa n waye fun ọpọlọpọ ọdun tabi oṣu ki aṣiri to tu.

Njẹ bawo wa ni awọn obi ṣe le fura tabi mọ pe, ọmọ wọn ọkunrin tabi obinrin ti n koju ifipabanilopọ?

Sẹ mọ pe ọpọlọpọ awọn ọmọ naa ni ki i le sọ fun ẹnikẹni nipa isẹlẹ adojutini naa, nitori pe nigba mi, ẹni to n fi ipa ba wọn lopọ yoo ti kilọ tabi halẹ mọ wọn pe, oun yoo pa wọn tabi fi iya jẹ wọn ti aṣiri naa ba fi tu sita.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRape: Oluwaseun Osowobi ní Commonwealth fún lámì ẹ̀yẹ ọ̀dọ́ tó pegedé jùlọ ní 2018

Onimọ kan nipa ihuwasi ẹda, to tun jẹ ajafẹtọ ọmọde, Temiloluwa Morounkeji, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, sọ diẹ lara awọn apẹẹrẹ to ṣeeṣe ki iru ọmọ bẹẹ maa fihan, ti iya rẹ si gbọdọ se akiyesi.

Awọn ami ti iya gbọdọ kiyesi pe wọn n fi tipa ba ọmọdebinrin lopọ:

 • Iru ọmọdebinrin bẹẹ yoo maa ni ibanujẹ ni gbogbo igba, yoo maa karijọ tabi ṣe ojo lati sọrọ sita
 • Ọmọ naa yoo maa binu nigba gbogbo, tabi maa hu awọn iwa to ju ọjọ ori rẹ lọ
 • Yoo maa ni idiwọ tabi maa ni ijakulẹ lẹnu ẹkọ rẹ, ti kii si ri i bẹ tẹlẹ
 • Yoo nira fun lati ni ọrẹ ti yoo maa ba sere
 • Iru ọmọ bẹẹ yoo maa ni irora to ṣajoji tabi to kọ lati lọ
 • Yoo maa la alakala lati sun tabi ko ma ri oorun sun lasiko to yẹ lai si idi kan pato
 • Ọmọde naa yoo maa wo su u, ti ọkan rẹ ko ni papọ, bo ba se n mu igba ati awo, ni yoo maa jabọ lọwọ rẹ pẹlu ibẹru
 • Ayipada nla yoo ba bi ọmọde naa se n jẹun deede, adinku lee ba isọwọ jẹun rẹ tabi ko pọ si
 • Iru ọmọdebinrin bẹẹ yoo maa sọ awọn ọrọ kan to ṣeesẹ ko fa ijiroro lori ọrọ ibalopọ ni gbogbo igba tabi ko yago ketekete si ijiroro to nii se pẹlu ibalopọ
 • Bẹẹ ni yoo tun maa ya aworan tabi kọ nkan nipa ibalopọ tabi maa la ala ibalopọ ni ọpọ igba
 • Ọmọ naa yoo maa ṣadeede ni ibẹru tabi sa fun irufẹ eniyan kan tabi agbegbe kan ti wọn ba ti fi tipa ba lopọ
 • Yoo kọ lati sọ ọrọ aṣiri kan to sọ fun agbalagba miran tabi ọmọde to ju lọ diẹ, fun ẹlomiran
 • Yoo maa sọ ọrọ nipa ọrẹ tuntun to ṣẹṣẹ ni, amọ to ju u lọ
 • Ọmọde naa yoo ṣadeede maa ni owo lọwọ, nkan iṣere tabi ẹbun lai si idi pataki fun, ti ko si ni jẹ eyi tawọn obi rẹ fun
 • Yoo maa roun n pe ara oun ko rẹwa to tabi pe oju oun ko dun wo, ti yoo si maa kiyesi ara rẹ nigba gbogbo
 • Iru ọmọ bẹẹ yoo maa hu iwa agbalagba ninu awọn iwa ati ise rẹ, ti yoo si maa fi òye nipa ibalopọ han
 • Nigba miran ti isẹlẹ ifipabanilopọ ba waye, ọmọde naa yoo maa ni irora ninu egungun, da ẹjẹ loju ara tabi ki nkan miran maa jade lati oju ara, iho idi, tabi ẹnu rẹ
 • Ọmọdebinrin ti ko tii balaga to ẹni ọkunrin yoo bẹrẹ si ni rin irinkurin tabi hu iwa agbere
 • Yoo sa kuro nile nigba ti isẹlẹ ifipa bani lopọ naa ba di lemọlemọ fun ninu ile to n gbe, ti ko si lee fara da isẹlẹ naa mọ.