World Malaria Day: Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ń mú àìsàn ibà pànìyàn?

Aworan ẹ̀fọn to n jẹ eniyan ni apa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹ̀fọn to ni kokoro ibà lara lo maa n pin

Bawo ni a ṣe le da ibà duro?

Bo tilẹjẹ wi pe aisan yii jẹ ohun to ṣe e dena, to si ni itọju, o ṣi n ṣeku pa ọpọlọpọ. Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ eto ilera ni agbaye, WHO, aisan iba n ṣeku pa ọmọde ni iṣẹju meji-meji, eniyan to le ni igba miliọnu si ni akọsilẹ wa pe o n ni aisan yii l'ọdun.

Lootọ ni igbogun ti ibà ti lọ soke sii daada lati bi ọdun mẹwaa, ṣugbọn ọ̀rọ̀ naa tun ti kọja agbara lati ọdun 2015: Abọ iwadi ajọ WHO nipa aisan ibà l'agbaye, to fi sita l'ọdun 2018 fihan pe ko fi bẹẹ si adinku ninu iye awọn to ni aisan ibà laarin ọdun 2015 si 2017.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aisan iba ṣe e dena, o si ṣe e tọju

Bi ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kẹrin ṣe wa a jẹ Ayajọ aisan iba l'agbaye, awọn nkan to yẹ ki o mọ nipa aisan naa ni yii.

  • Ibà jẹ aisan to maa n dunkoko mọ ẹ̀mí, eyi ti kokoro aifojuri mẹrin n fa: P. falciparum, P. malariae, P. ovale ati P. vivax.
  • Awọn kokoro aifojuri yii maa n wọ ara eniyan lasiko ti abo ẹ̀fọn ti wọn tun maa n pe ni ''olokoowo iba'' ba jẹ eniyan.
  • Aisan ibà ṣe e dena, o si ṣe e tọju.
  • L'ọdun 2017, awọn eniyan to to okoolerugba din ẹyọkan lo ni ibà ni orilẹede mẹtadinlaadọrun (Akọsilẹ ajọ WHO)
  • Eniyan to to ojilenirinwo din maarun, 435,000, ni ibà pa l'ọdun 2017
  • Ilẹ Afirika ni aisan ibà pọ si ju - l'ọdun 2017 nikan, ìdá mejilelaadọrun ni awọ̀n to tni ibà ni Afirika, ìdá mẹtalelaadọrun si lo pa.
  • Apapọ owo ti wọn naa lati fi gbogun ti ibà le biliọnu mẹta Dọla ( $3.1bn) ni 2017.

Awọn apẹẹrẹ ibà

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ara gbigbona, otutu, ati ori fifọ̀ ni awọn apẹẹrẹ ti ibà kọkọ maa n fihan

Awọn apẹẹrẹ ibà - ara gbigbona, ori fifọ, ati otutu - eyi to maa n fi ara han laarin ọjọ mẹwaa si mẹẹdogun ti ẹ̀fọn to n pin ibà ba jẹ ni

Awọn apẹẹrẹ naa le ma han pupọ, ṣugbọn ti ko ba si itọju laarin wakati mẹrinlelogun, ibà ti kokoro aifojuri 'P. falciparum' ba fa le yọri aisan to n pani.

Taa lo wa ninu ewu?

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ wẹwẹ to n gbe ni awọn agbagbe ti aisan ibà wa n bẹ ninu ewu nini aisan naa

L'ọdun 2017, bi ilaji awọn to wa ni aye lo wa ninu ewu nini aisan iba.

Awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko to ọdun maarun lo wa ninu ewu ju: L'ọdun 2017, awọn lo ko ìdá mọkanlelọgọta(266,000) ninu awọn ti ibà pa l'agbaye.

Awọn to tun wa ninu ewu to l'agbara ni awọn alaboyun, ati awọn ti agọ-ara wọn ko l'agbara to lati gbogun ti aisan.

Awọn agbegbe wo lo wọpọ si ju?

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aisan ibà wa jake-jado awọn agbegbe to n aisko ojo ati ọ̀gbẹlẹ̀, ṣugbọn Afirika lo pọ si ju

Gẹgẹ bi ajọ WHO ṣe sọ, ọpọ̀ aisan iba ati iku to waye nipa a rẹ n ṣẹlẹ ni agbgbe ilẹ olooru Afirika, ṣugbọn awọn agbegbe kan ni South-East Asia, Eastern Mediterranean, Western Pacific, ati nilẹ America naa wa ninu ewu.

L'ọdun 2017, orilẹede maarun lo fẹ ẹ ko ilaji ninu awọn to ni ibà kaakiri agbaye: Nigeria (25%), Democratic Republic of the Congo (11%), Mozambique (5%), India (4%) ati Uganda (4%).

Bi aisan ibà ṣe n wọ inu ara

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ẹ̀fọn ti eyikeyi ninu oriṣi kokoro aifojuri Plasmodium ba wa lara arẹ lo maa n pin aisan naa

Ni ọpọ igba, aisan iba maa n wọ ara ti abo ẹ̀fọn (Female Anopheles) ba jẹ eniyan - oriṣi abo ẹ̀fọ̀n to wa le ni irinwo, ninu eyi ti bi ọgbọ̀n jẹ 'olokoowo iba' to jẹ pataki.

Laarin irọlẹ si idaji si ni gbogbo awọ̀n olokoowo pataki yii maa n jẹ eniyan.

Inu omi ni abo ẹ̀fọ̀n yoo ye ẹyin rẹ si, eyi ti yoo dagba di ẹ̀fọn; abo ẹ̀fọn maa n wa ẹ̀jẹ̀ lati fi bọ́ awọn ẹyin wọn.

Ọna lati dena iba

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán L'ọdun 2017, bi ilaji awọn to wa ni aye lo wa ninu ewu nini aisan iba.

Ajọ WHO la awọn ọna abayọ to n ṣiṣẹ silẹ fun gbogbo eniyan to wa ninu ewu nini aisan iba.

Oriṣi ọna meji - àpò to ni oogun apẹfọn ati fi fi oogun apẹfọn fin inu ile - mejeeji maa n ṣiṣẹ daada l'oriṣiriṣi igba

Sisun si abẹ apo apẹfọn le mu adinku ba ifarakanra laarin ẹ̀fọn ati eniyan nipa pipese idiwọ to ṣe e fi oju ri ati oogun to le kapa kokoro.

Lilo oogun apẹfọn jẹ fi fi iru oogun bẹ fin ile lẹẹkan tabi ẹẹmeji l'ọdun.

A tun le dena aisan iba nipa lilo awọn oogun to le gbogun ti iba fun awọ̀n arinrinajo, alaboyun, awọn obinrin ati awọn ọmọde.

Ayẹwo ati itọju aisan iba

Early diagnosis and treatment yields best results T

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ti tete ṣe ayẹwo ati itọju maa n so eso to dara ju

Aisan iba ṣe e tọju - ayẹwo le ṣe afihan aisan iba ninu ara laarin ọgbọ̀n iṣẹju tabi ko maa to bẹ.

Gẹgẹ bi ajọ WHO ṣe sọ, ti tete ṣe ayẹwo ati itọju fun aisan ibà maa k'apa rẹ, o si tun maa n dena iku ati itankalẹ aisan iba.

Itọju to dara ju to wa fun un, paapa fun aisan ibà ti kokoro aifojuri P. falciparum ba fa, ni ' artemisinin-based combination therapy (ACT).'

Ibà ti agbara oogun apakokoro ati egboogi ko ka

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ayẹwo ẹjẹ gbọdọ maa waye l'oore-koore lati tọpinpin ibà ti agbara egboogi ko ka

Ajọ WHO ti fi ikil sita pe abo ẹ̀fọn ti n fi agbara han lera-lera pe agbara egboogi ati oogun apakokoro ko ka oun - to si n mu idiwọ ba iṣẹgun lori iba.

Ibẹru to wa ni pe o ṣeeṣe ki awọn irinṣẹ idena ati amojuto to wa bayii le dawọ iṣẹ duro.

Akọsilẹ tuntun nipa aisan ibà l'agbaye fihan pe orilẹede mejidinlaadọrin lo jábọ̀ pe agbara oogun apẹfọn ko ka ẹfọn l'awọn akoko kan laarin ọdun 2010 si 2017.

Bakan naa ni iba ti agbara eegbogi ko ka naa n waye ni gbogbo igba.

Ajọ WHO sọ pe egboogi to n dena iba ṣe koko fun amojuto ati iparun aisan naa - o si n polongo ṣiṣe titọ pinpin ni awọn orilẹede ti ibà ti wọpọ ju.

Afojusun ni lati ri i daju pe wọn tete ri ibà ti agbara egboogi ko ba ka, ki wọn si kọju ija si ni kiakia ati l'ọna to yẹ.