Brazil: Àwọn ọlọ́pàá tí f'òfin mú ẹyẹ tó n tú àṣírí fún àwọn ọ̀daràn

Ẹyẹ ayekootọ

Ẹyẹ ayekootọ kan l'orilẹede Brazil ti wa ni ahamọ ọlọpaa nitori ẹsun pe o maa n ṣe ofofo fun awọn oniṣowo oogun oloro ti awọn ọlọpaa ba ti fẹ wa mu wọn.

Awọn oniṣowo oogun oloro naa ti kọ ẹyẹ ọhun lati pariwo ''mama, ọlọpaa'' ni ede Pọtugi lati jẹ ki awọn ọdaran naa mọ pe awọn ọlọpaa n bọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa gbagbọ pe awọn oniṣowo naa ''mọọmọ kọ ẹyẹ ayekootọ naa ni ofofo ṣiṣe ni,'' nitori lọgan ti awọn ọlọpaa ba ti sun mọ ile ti awọn oloogun oloro naa wa, ni yoo bẹrẹ si ni i pariwo.''

Lẹyin ti ọwọ ọlọpaa tẹ ẹyẹ naa, wọn fi pamọ si ahamọ wọn lati fi ọrọ wa a l'ẹnu wo lori ohun to mọ nipa awọn oniṣowo oogun oloro ọhun.

Dokita ẹranko kan, Alexander Clark, ti awọn ọlọpaa gba lati fi ọrọ wa ẹyẹ naa lẹnuwo sọ pe ''niṣe ni ayekootọ kọ̀ lati sọ ohunkohun.''

Ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe awọn yoo fa ẹyẹ naa le awọn alaṣẹ ibugbe ẹranko to wa ni agbegbe naa lọwọ nibi ti yoo wa fun oṣu mẹta lati kọ́ bi yoo ṣe maa fo, ko to o di pe wọn yọnda rẹ.