Loom Money Nigeria: Ṣáájú Loom Money Nigeria, àwọn ètò sogún-dogójì púpọ̀ ti ta pàù lórílẹ̀èdè

Ami idanimọ Loom

Ajọ to n risi eto idokowo l'orilẹede Naijiria ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria lati maa kopa ninu eto sogun-dogoji tuntun to gbode, 'Loom Money Nigeria'.

Eto 'idokoowo' naa lo bẹrẹ laipẹ yii, to si jẹ pe ori ẹrọ ayelujara Facebook ati Whatsapp ni awọn ọmọ ẹgbẹ ti n ṣe 'kata-kara.

Ajọ NSE sọ pe oun ko ni akọsilẹ tabi iforukọsilẹ kankan nipa eto naa, ati pe o lewu fun ẹnikẹni to ba n fi owo rẹ ṣe e.

Bakan naa ni banki apapọ Naijiria naa ti fi ikilọ sita lori eto yii kan naa.

Bawo ni idán eto 'idokowo yii ṣe n lọ?

Olukopa kan to ba BBC sọrọ, Arabinrin Oyindamọla, sọ pe oun ti fi ẹgblrun meji Naira t'oun fi bẹrẹ idokoowo pa ẹgbẹrun mẹrindinlogun Naira.

O ni amọ imọran oun ni pe 'ki awọn eniyan o maa fi owo to pọ dokowo, nitori pe ti o ba ti bẹrẹ, ka ni o fi ọgọrun ẹgbẹrun Naira bẹrẹ, iwọ fun ra a rẹ ni yoo wa eniyan mẹjọ mi i ti yoo da owo rẹ pada fun ọ ti asiko rẹ ba to lati 'ko àjọ'. Eyi si nira pupọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Arabinrin Oyindamọla sọ pe ''ohun to mu eto yii yatọ si MMM ni pe o ko ni i da owo mi i titi ti o fi gba owo rẹ lọwọ eniyan mẹjọ ti o ba mu wa.''

Ẹlomii t'oun naa n ṣe e sọ pe, eto naa ki i ṣe sogun-dogoji rara, ''o da bi àjọ dida ni.''

Tẹ o ba gbagbe, ẹ o ranti pe igba akọkọ kọ niyii ti eto sogun-dogoji yoo gbajumọ ni Naijiria, ti ọpọlọpọ rẹ kii si pẹ to fi n kogba wọle lẹyin ti awọn eniyan ba ti ko obitibiti owo le e lori.

Ẹ jẹ ka ran ara wa leti diẹ lara awọn eto owo kiakia naa, ati ọna ti wọn gba pa ọpọlọpọ ọmọ Naijiria l'ẹkun.

Mavrodi Mundial Money-box (MMM)

Eto sogun-dogoji MMM jẹ agbekalẹ ileeṣẹ orilẹede Russia kan to de si orilẹede Naijiria l'ọdun 2015, botilẹjẹ pe o ti wa lati ọdun 1989.

Lootọ ni iroyin jade nipa bi MMM ṣe da iyẹpẹ si gaari awọn eniyan ni awọn orilẹede kan, eyi ko da awọn ọmọ Naijiria duro lati ma ko owo wọn le e lori nitori ireti pe 'ẹyẹ awọn yoo ti fo ki igi o to o da'.

MMM ṣeleri lati fun awọn oludokowo ni ele ìdá ọgbọn (30%) lori iyekiye ti wọn ba fi dokowo.

Image copyright PIUS UTOMI EKPEI
Àkọlé àwòrán MMM ṣeleri lati fun awọn oludokowo ni ele ìdá ọgbọn (30%) lori iyekiye ti wọn ba fi dokowo.

Amọ ṣaa, iyalẹnu lo jhẹ nigba ti eto naa pada foriṣanpọn l'oṣu Kejila, ọdun 2016, ti ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ Naijiria si padanu owo wọn.

Iroyin jade paapa nipa awọn mi i to gbẹmi ara a wọn nitori òfò wọn.

Claritta

O ku diẹ ki MMM o lana ni Claritta de. Eto sogun-dogoji Claritta ni tiẹ naa fẹ ẹ fara jọ MMM. Ẹni to ba fẹ ẹ kopa yoo kọkọ san, fun apẹẹrẹ, ẹgbẹrun kan Naira fun olukopa mi i, ti awọn ọmọ ẹgbẹ mẹẹrin mi i yoo si da ẹgbẹrun kọọkan Naira si apo asunwọn ti ẹ naa laarin ọjọ meje.

Amọ, o ṣeni laanu pe eto yii ko pẹ rara ti o fi ta pau bi i guguru. Ọpọ olukopa ni ẹni da owo fun wọn titi ti eto naa fi 'jona., ti oju opo itakun agbaye awọn to da a silẹ ko si ṣiṣẹ mọ di asiko yii.

Ultimate Cyclers

Ọmọ ilẹ Amẹrika kan niroyin sọ pe o ni eto 'idokowo' yii, ti eto naa si ti pa orukọ da laimọye igba.

Eto naa gba ilana kan naa pẹlu Claritta.

Get help Worldwide

Get Help Worldwide ṣeleri ajẹpọnnula èrè ìdá ọgbọn si aadọta (30%-50%) fun olukopa loṣooṣu.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn mi i to tun ti wa ni Penny Wise, Swiss Golden, Twinkas, Plan well, Nopecsto ati bẹẹbẹ lọ.

Ìdá ọgbọn fun ọ ti o ba fẹ ẹ gba owo rẹ ati ele ni owo Naira, nigba ti wa a gba ìdá aadọta ti o ba fẹ ẹ gba ni owo igbalode 'Bitcoin.'

Oun naa ti foriṣanpọn bayii.

Awọn mi i to tun ti wa ni Penny Wise, Swiss Golden, Twinkas, Plan well, Nopecsto ati bẹẹbẹ lọ.