Lagos Beggars: Bí wọ́n ṣe jí ọmọ yìí gbé láti máa fi ṣiṣẹ́ bárà l'Eko

Aworan ọmọdekunrin to n gun kẹẹkẹ
Àkọlé àwòrán Ohun kan ti ẹbi rẹ mọ ni pe wọn lo gun kẹkẹ lọ sita. Alọ rẹ ni wọn ri, wọn ko ri abọ rẹ fun ọdun mẹfa.

Samuel Abdulraheem ko ranti ọjọ tabi bi wọn ṣe ji i gbe nile awọn obi rẹ nilu Kano nigba o wa ni ọmọ ọdun meje.

Ohun kan ti ẹbi rẹ mọ ni pe wọn lọ gun kẹkẹ lọ sita. Alọ rẹ ni wọn ri, wọn ko ri abọ rẹ fun ọdun mẹfa.

Wọn wa a fun ọpọ igba pẹlu igbagbọ pe wọn yoo ri lọjọ kan nitori ẹni to ku ati ẹni to nu a pade lọjọ kan, amọ nigba to ṣe diẹ, wọn gba fun Ọlọrun.

Baba Samuel jẹ oniyawo mẹrin, o si bi ọmọ mẹtadinlogun.

Botilẹjẹ pe iya Samuel ati baba rẹ ti kọ ara wọn silẹ, Samuel ni ẹgbọn obinrin kan, ti awọn mejeeji jọ fẹran ara wọn daada nigba naa.

Àkọlé àwòrán Samuel ni iya gbe lọwọ yii lọdun diẹ ṣaaju ki wọn o to o jigbe.

Ẹgbọn rẹ obinrin yii, Firdausi Okezie, wa nileewe giga fasiti lasiko ti iṣẹlẹ yii waye. Lẹyin ọdun diẹ, o pari ẹkọ rẹ. O si wa iṣẹ aje wa si ilu Eko.

Dide to de si Eko, o yipada di ẹlẹsin Kristiẹni. O si bẹrẹ si ni lọ si ijọ Living Faith Chapel, ti a tun mọ si Winners Chapel.

Ijọ naa maa n ṣe ipagọ ọlọdọọdun l'oṣu Kejila ọdun. Iru ipade yii ni Firdausi lọ ni ọdun 2000.

Titi di asiko naa, ko ti i ri iṣẹ kankan ṣe. Eyi lo mu ki o gba ọkan lara awọn ìsọ ti ijọ naa maa n fun awọn ọmọ ijọ lati fi ta ọja lasiko ti ipagọ ba n lọ lọwọ.

Nibi ti kafinta kan ti n ba Firdausi kan pako ti yoo to aṣọ adirẹ to n gba lati ọwọ iya rẹ fun tita, lo ti taju kan, to si ri ọkunrin kan to n tọrọ bara.

Gbigbe ti yoo gbe oju soke, o ṣakiyesi pe ọmọkunrin to n mu onibara naa rin jọ aburo rẹ, ti wọn ti n wa fun ọdun pipẹ, t'oun ti aṣọ idọti lọrun.

Ariwo to pa nitori idunnu mu ki awọn eniyan o pe le wọn lori, wọn si doola aburo rẹ.

Àkọlé àwòrán Ariwo to pa nitori idunnu mu ki awọn eniyan o pe le wọn lori, wọn si doola aburo rẹ.

A ṣe bi wọn ṣe ji Samuel gbe nilu Kano, ilu Eko ni wọn gbe e wa.

Ti obinrin kan to ra a lọwọ wọn si fi maa n ṣọfa fun awọn onibara ti yo maa mu kiri.

Ẹẹdẹgbẹta Naira ni obinrin naa maa n gba lasiko naa lọwọ onibara kọọkan to ba fẹ lo Samuel.

Samuel nikan kọ lo n ṣe iru iṣẹ yii ninu ile ti obinrin naa n gbe. Awọn alajọgbele rẹ kan naa n lo awọn ọmọde fun iṣẹ naa.

Àkọlé àwòrán Samuel nikan kọ lo n ṣe iru iṣẹ yii ninu ile ti obinrin naa n gbe. Awọn alajọgbele rẹ kan naa n lo awọn ọmọde fun iṣẹ naa.

Lẹyin ti wọn ri Samuel, ko wulẹ pada si ilu Kano mọ. O n gbe ni ọdọ ẹgbọn rẹ, o si pada sileewe alakọbẹrẹ bo tilẹ jẹ pe o ti dagba ju, ti ọpọ ileewe si kọ ọ.

Laarin oṣu mẹta pere, Samuel ti bọ si kilaasi kẹrin lati ikinni. Laarin ọdun kan, o wọ ileewe girama.

Image copyright Firdausi Okezie
Àkọlé àwòrán Samuel ati ẹgbọn rẹ lọjọ ti o n ṣe igbeyawo, lẹyin bi ọdun meji to ri i.

Ọdun mẹta pere ni Samuel lo nileewe girama to fi ṣe idanwo JAMB bọ si Fasiti Ahmadu Bello to wa ni Zaria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionContortionist: Mo lè gbé ìfun mi pamọ́ ki n tún se èémí!

Ṣugbọn o ṣeni laanu pe iwe ti Samuel mọ daada naa ni yoo fi opin si iwe kika a rẹ.

Ọdun kẹrin lo wa nileewe nigba ti ọwọ tẹ ẹ pe o joko ṣe idanwo fun akẹkọọ mi. Wọn si le e kuro nileewe naa.

Image copyright Samuel Abdulraheem
Àkọlé àwòrán Samuel sọ pe iriri ti oun ni l'oko ẹru lo sọ oun di ẹlẹyinju aanu.

Samuel to ti pe ẹni ọgbọn ọdun bayii, n ṣiṣẹ alamojuto ile kikọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionToma Unu: Ọmọbìnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ya àwọran nítori pe ó ni ìpènija ọpọlọ

''Nigba ti nkan ba dara fun mi tan, mo ni ireti lati tẹsiwaju eto ẹkọ mi. O sọ pe imọ ijinlẹ nipa ẹrọ ayelujara si ni yoo wu oun lati kọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'A fẹ́ kí àwọn sẹ́nétọ̀ gba ẹlòmíì láàyè'

Samuel ni oun ko kabamọ lori iriri oun ni ahamọ ati pe o jẹ ohun ibanujẹ fun oun. O gbagbọ pe awọn iriri naa lo sọ ọ di oloju aanu, ti kii fi oju kere ẹni to ba nilo iranlọwọ tabi jẹ onibara.

Awọn aworan inu itan yii wa lati ọwọ oṣiṣẹ BBC, Manuella Boloni