"Àlùfàá méjì wà lára àwọn mẹ́rin tó fi ipá bámilòpọ̀"

obinrin Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Olukọ kan tun bamilopọ pẹlu ipá.

Nadia (ti a fi orukọ bo ni aṣiri) jẹ́ ẹni ọdun mọkanlelogun, to si n siṣẹ nileesẹ kan nilu Yaoundé Cameroun, ti koju ifipanilopọ lẹẹmẹrin ọtọọtọ.

Mọlẹbi rẹ kan, alufaa meji ati olukọ kan ni awọn mẹrin to ka pe wọn ti fipa ba oun lo pọ rí.

Nadia ti gbiyanju lati gba ẹmi ara arẹ ni ọpọlọpọ igba ko to padé alaanu kan.

Lọjọ ti ayipada maa de ba a, O pade ajọ alaanu kan to ran an lọwọ lati pada si igbe aye ọtun.

Nibayii, o n sọ itan igbe aye rẹ fun awọn ọdọmọbinrin to ba koju ifipabanilopọ lati mọ pe, kii ṣe awọn nikan ni ọrọ naa kan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAbdulfatah Ahmed: Àwọn Kwara fẹ́ dán ilé ọkọ kejì wo ni lásìkò yí

Fifi ipa ba awọn obinrin ati ọmọde lo pọ wọpọ ni Cameroon, ti awọn ti wọn fi ipa ba lo pọ kii ṣi jẹ ki ẹnikẹni mọ nipa rẹ.

Laarin ọdun 1970 si 2008, obinrin to le ni irinwo ẹgbẹrun ni wọn ti fi ipa ba lo pọ ni Cameroon, gẹgẹ bi akọsilẹ ileeṣẹ German Technical Cooperation lasiko to ṣe ifilọlẹ ipolongo tako ifipabanilopọ.

Nadia sọ fun BBC pe iṣoro oun bẹrẹ nigba ti oun wa ni ọmọ ọdun mẹtala.

O ni 'ibatan mi lo fi ipa bamilopọ, mi o si sọ ọrọ naa fun ẹnikẹni. Ṣugbọn, o jẹ ọgbẹ ọkan fun mi.

Nigba ti mo pinnu lati sọ fun alufaa ijọ Katoliiki ti a n lọ, niṣe l'oun naa tun fi ipa bamilopọ.

Image copyright VOH
Àkọlé àwòrán Nadia pade ajọ Voice of Hope, wọn si n ran an lọwọ lati maa sọ itan aye rẹ ni awọn nileewe.

'Ọrọ naa le debi pe, mo bẹrẹ si ni lo oogun oloro ati siga. Koda, mo ni iṣoro nileewe debi i pe wọn fẹ le mi danu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTani otutu ma n mu ju laarin Ọkunrin ati Obinrin?

Olukọ kan tun bamilopọ pẹlu ipá.

Mo wa bi ara a mi leere pe, ṣe emi nikan ni?''

"Bi ẹẹmẹwaa ni mo gbiyanju lati pa ara mi, nitori pe ko si ẹni kankan nilee wa to mọ tabi ni òye nkan ti mo n la kọja.

Image copyright Marvi Lacar
Àkọlé àwòrán "Àlùfàá méjì wà lára àwọn mẹ́rin tó fi ipá bámilòpọ̀"

Ẹgbọn mi ọkunrin a ti ẹ tun maa na mi, ibaṣepọ pẹlu awọn obi mi paapa ko dara. Sibẹsibẹ, mi o sọ fun ẹnikẹni."

Ko rọrun lati sọ fun ẹnikẹni nigba naa. Ṣugbọn, o ti ye mi bayii pe o ṣeeṣe ki n ri iranlọwọ ka ni mo sọrọ sita nigba naa."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#Queen Dihya: Obinrin tó gbógun tàwọn agbésùnmọ̀mí ni Algeria

Ọpọ eniyan bi i Nadia lo wa ni Cameroon ti wọn ti fi ipa balopọ. Ko si ti i ju oṣu mẹta lọ ti iroyin jade pe awọn kan fi ipa ba ọmọde mẹta lopọ. Ọkan lara wọn ku, wọn n ṣe isẹ abẹ fun ọkan lara wọn lọwọ nileewosan.

Akọsilẹ ajọ to n ṣewadi nipa eto ilera ni Cameroon, Cameroon Health and Demographic Survey, DHS, fihan pe ìdá mọkanlelogun obirin to wa ni Cameroon lo ni ibalopọ akọkọ nipa ifipabanilopọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJiti Ogunye: Ìjọba àkóbá lológun gbé kalẹ̀ ni 1999
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObinrin Akansẹ: Ẹsẹ kiku bi ojo kọ mi lati di alagbara