June 12 in Nigeria: Wo àwòrán pápá ìṣeré MKO Abiola National Stadium

Àkọlé àwòrán Buhari ti fi ori MKO Abiola pe papa iṣere Abuja National Stadium.

Lẹyin ogun ọdun ti ọrọ JUNE 12 ṣẹlẹ ni Naijiria, aarẹ Buhari ṣe iranti oloogbe MKO Abiọla.

Akọni to dije dupo aarẹ Naijiria labẹ ẹgbẹ oṣelu SDP eyi ti ijọba ologun Naijiria wọgile lọdun 1993 ni wọn n ṣe iranti rẹ lasiko yii ni Naijiria.

Bayii, Ijọba Naijiria ti ya ọjọ kejila, oṣu kẹfa ọdun sọtọ gẹgẹ bii ayajọ ọjọ iṣejọba awa ara wa.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Buhari kede June 12 lọjọ iṣejọba alagbada

Bakan naa ni aarẹ Muhammed Buhari kede pe orukọ Basọrun Moshod Kashimaawoo Olawale Abiola ni a o maa fi pe papa iṣere Abuja lati isinyi lọ.

Àkọlé àwòrán MKO Abiola Stadium

Lọdun 2003 ni wọn bẹrẹ si ni lo papa iṣere yii nilu Abuja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJune 12: Lekan Alabi ní kí ọmọ Naijiria rántí àwọn akọni ìjọba àwa-arawa

Oloye Oluṣẹgun Obasanjọ lo kọ papa iṣere yii lasiko to n dari Naijiria labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ọpọlọpọ lo ni o dabi pe ijọba Naijiria ti moju kuro lara papa iṣere naa tipẹ diẹ bi wọn ṣe ṣiju kuro lara papa iṣere to wa ni ipinlẹ Eko.

Àkọlé àwòrán Oriṣii papa iṣere lo wa ni Naijiria

Ọpọlọpọ igba lawọn ọmọ Naijiria maa n binu pé awọn maalu ati awọn darandaran ti sọ papa iṣere Abuja yii di ile wọn.

Àkọlé àwòrán Papa sere yii ko le duro mo legbe awon akegbe re nile okeere rara

Arugbo ṣoge ri ọrọ papa iṣere Abuja yii.

Naijiria ti loo ri figba alejo idije ere bii ti All African Games lọdun 2003 ti wọn kọkọ fi ṣide.

Àkọlé àwòrán Tayọtayọ ni aarẹ Buhari fi kede pe orukọ MKO Abiola ni wọn yoo maa fi pe papa iṣere ọhun

Onworan ẹgbẹrun lọna ọgọta ni papa iṣere yii le gablejo rẹ nijoko kan ṣoṣo.

Àkọlé àwòrán Papa iṣere yii lo gbalejo idije Super Eagles lọdun 2003 nigba ti ijọba ṣiju kuro ni papa iṣere Eko

Papa iṣere yii ni ibudo ìwẹ̀ igbafẹ tinu ile, o ni papa fun gbigba bọọlu ẹlẹyin tori tabili, bọọlu alajusawọn, ati bọọlu ẹlẹyin alafiigi gba.

Lori papa iṣere yii naa ni ogunlọgọ ọdọ Naijiria ti lọ pade fun idanwo ati gba iṣẹ aṣọbode lọdun 2015.

Àkọlé àwòrán Papa isere Abiola tuntun

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo n parọwa fun ijọba apapọ lati ṣe gbogbo atunṣe si papa yii ko le ba ẹgbẹ pé.

Wọn gba pe ohun to ba too pe ori akọni lo yẹ ki a fi pee bi awọn to ku ni agbaye ṣe n ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFIFA 2019: Ọdún 1991 làkọ́kọ́ irú rẹ̀ ní àgbáyé