Ọlọ́pàá Eko: Afurasí náà ní ẹnìkan ló bẹ òun lọ́wẹ̀ láti lọ gba ilẹ̀ onílẹ̀

Ojo Adeṣọla, afurasi ọdaran Image copyright Nigerian Police
Àkọlé àwòrán Awọn ọlọpaa ba ibọn agbelẹrọ mẹẹrin ati ọta ibọn mejidinlogoji ninu ọkọ bọọsi naa.

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ igara ọmọ onilẹ kan, to tun jẹ agbanipa nipinlẹ naa.

Atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Bala Elkana fi sita ni, ọwọ tẹ afurasi naa, Ojo Adeṣọla, ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2019, ni nkan bi aago mẹjo owurọ ni adugbo Alagbado nipinlẹ Eko.

''Ọwọ awọn ọlọpaa to wa ni ẹka ileeṣẹ naa ni Alagbado tẹ Adeṣọla lasiko to n ko nkan ija lọ pẹlu ọkọ bọọsi funfun kan ni oju ọna Amikanle, Alagbado.''

Awọn ọlọpaa ba ibọn agbelẹrọ mẹrin ati ọta ibọn mejidinlogoji ninu ọkọ bọọsi naa.

Bala sọ pe, ẹni ọdun marundinlaadọta ọhun jẹ ọmọ ẹgbẹ ikọ̀ alagbara kan to maa n gba ilẹ onilẹ, to si tun n ṣiṣẹ agbanipa nipinlẹ Ogun ati Eko.

'Niṣe ni wọn n ṣe ara wọn bi balogun, to maa n duro de ẹnikẹni to ba tile san owo isẹ wọn, lati gba ilẹ onilẹ pẹlu ipá. Koda, wọn maa n pa tabi pa awọn to ni ilẹ lara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIba Gani Adams: Bẹ́ẹ gbé màláíkà kan lọ sí Aso Rock, kò lè ṣàṣeyọrí

O ni afurasi naa sọ pe 'ẹnikan lo bẹ awọn niṣẹ lati gba ilẹ lọwọ awọn kan ni ilu Ẹpẹ. Ati pe oun n lọ fi ọkọ gbe awọn iyoku oun fun iṣẹ naa ni ọwọtẹ.''

Nibayii, ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n wa awọn akẹẹgbẹ rẹ maarun to ti salọ.