Skin Bleach: Èyí ni ọ̀nà tí àwọn obìnrin n gbà kó ara wọn sí wàhálà nítorí ara bíbó

Obinrin India kan n ṣe itọju oju rẹ ni ṣọọbu asaraloge kan ni New Delhi Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ miliọnu eniyan, papa awọn obinrin ni Asia ati Africa lo n gba oriṣiriṣi ọna lati di eniyan pupa.

Ara bíbó èrè wo ni àwọn eeyan n rí níbẹ̀?

Ọmọbinrin yii, Shiroma Pereira (ti a fi orukọ bo ni aṣiri), n mura fun ayẹyẹ igbeyawo rẹ.

Lara imurasilẹ rẹ gẹgẹ bi ọpọ ṣe maa n ṣe ni South Asia, ni pe o pinnu lati bo ara rẹ ṣaaju ọjọ igbeyawo. O ni ireti aàwọ ara to n dan, to si rẹwa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCerebral Palsy: àrùn tó n gba omijé lójú ẹni láìnídìí

Oṣu meji ṣaaju ọjọ igbeyawo, o lọ si ṣọọbu aṣaraloge kan, wọn si fun un ni ipara kan lati mu ki ara rẹ o pupa.

Lẹyin to lo ipara naa fun ọsẹ kan, oju rẹ pupa.

O sọ fun BBC Sinhala pe, ''mo fẹ ki ara mi o pupa, ṣugbọn ṣe ni gbogbo aàwọ mi jona."

Niṣe lo fi gbogbo asiko to yẹ ko fi maa gbaradi fun igbeyawo, ṣe itọju ara rẹ eyi to n gba asiko rẹ ati owo rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àjẹ́, eégún, kí ni wọn ò pè mí tán tórí Vitiligo lára mi'

Ipara ti wọn fun un ko si lara awọn eroja iṣaraloge ti wọn fi ọwọ si ni Sri Lanka.

Awọn kan lo n ko wọn wọle lọna ti ko ba ofin mu, ti wọn si n ta a ni ọja pade mi ni kọọrọ.

Àkọlé àwòrán Titi di asiko yii lati bi ọdun kan o le, àwọ ara Pereira ko ti i bọ sipo.

Iṣoro ara bibo kii ṣe iṣoro to n koju Sri Lanka nikan. Ọpọlọpọ miliọnu eniyan, paapa awọn obinrin ni Asia ati Afrika lo n gba oriṣiriṣi ọna lati di eniyan pupa.

Odiwọn ọja eroja ibora l'agbaye to biliọnu marun un Dọla ($4.8bn) lọdun 2017, igbagbọ si wa pe yoo di ilọpo meji nigba ti yoo ba fi di ọdun 2027.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn eroja yii pe oriṣiriṣi; ọṣẹ, ipara, ororo, tabilẹti oogun ati abẹrẹ.

Awọn eroja yii pe oriṣiriṣi; ọṣẹ, ipara, ororo, tabilẹti oogun ati abẹrẹ, ti wọn ṣe lati le da iṣẹ eroja melanin, to n sọ iru awọ ti eniyan yoo ni, duro.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsun Supreme: Àwọn èèyàn Ọṣun rọ Oyetọla láti jẹ́ kí àsìkò rẹ̀ tú aráàlú lára

Gẹgẹ bi ajọ eto ilera l'agbaye, WHO, ṣe sọ, obinrin mẹrin ninu mẹwaa nilẹ Afrika lo n lo awọn eroja ibora.

Nilẹ Afrika, orilẹ-ede Naijiria ni wọn ti n lo eroja ibora julọ. Awọn obinrin to n bora jẹ ìdá mẹtadinlọgọrin.

Orilẹ-ede Togo lo tẹle e, pẹlu ìdá mọkandinlọgọta, ati South Africa pẹlu ìdá mẹtadinlogoji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionA nilo agọ ọlọpa ni Orin Ekiti fún aabo wa -Falua

Ni Asia, awọn obinrin ìdá mọkanlelọgọta lo n bora ni India, ti ìdá ogoji si n lo wọn ni China.

Lọdun to kọja, awọn alaṣẹ l'orilẹ-ede Ghana kilọ fun awọn alaboyun lati dẹkun lilo oogun ibora to ni eroja antioxidant glutathione.

Awọn obinrin l'orilẹ-ede naa n lo oogun naa pẹlu ireti pe yoo mu ki ara ọmọ inu wọn o pupa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn ọ̀dọ̀ ti ń gbógun ti ara bíbó, ṣùgbọ́n ó ṣì wọ́pọ̀

Orilẹ-ede South Africa ní awọn ofin alagbara to gbogun ti ara bibo.

Gambia, Ivory Coast, ati Rwanda ti fi ofin de awọn eroja ibora to ni hydroquinone ninu.

Bi o ṣe maa nipese eroja melanin ku ninu ara, naa lo le ba àwọ ara jẹ.

Ajọ to n risi ọrọ aàwọ ara ni orilẹ-ede Britain sọ pe, ''awọn ohun to ba ni hydroquinone ninu ṣe e lo lati ṣe iwosan awọn aarun aawọ ara kan, labẹ amojuto onimọ nipa àwọ ara, ti yoo si so eso rere.

Ajọ naa sọ pe ''ko si ọna 'otitọ' kankan lo le mu ki gbogbo ara pupa.''

Ṣugbọn, ọpọlọpọ awọn obinrin lo maa n ra awọn eroja ibora lai gba itọni tabi ilana lọwọ onimọ nipa eto ilera.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Oriṣiriṣi akoba ni kẹmika ibora maa n ṣe fun ara.

Wọn le ni ipa bi i :

Ara yiyun ati wiwu

Ara tita tabi jijajẹ

Ati ki àwọ ara o maa bo

(Orisun -NHS UK)