Nigeria Army: Ta ni Ọgágun àgbà Lamidi Adeosun tó ṣẹṣẹ gba ìgbága?

Lamidi Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Lamidi Adeosun di ọga agba ninu iṣẹ ologun

A bi Ọgagun Lamidi Adeọṣun ni ọjọ Kejilelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 1963 nijọba ibilẹ Olaoluwa nipinlẹ Osun, lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.

Ojọ Kẹrin, oṣu Keje, ọdun 1983 lo darapọ mọ iṣẹ ologun, to si gba igbega titi to fi di ọgagun agba Major General lọjọ Kẹrin, oṣu Keje, ọdun 2014.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ogagun Lamidi ti ṣiṣẹ ni awọn ẹka iṣakoso ati ni oju ogun fun ọpọlọpọ ọdun.

O ti dari awọn ọmọ ogun ilẹ lẹkun Keje ileesẹ ologun ilẹ wa, (7 Division), to wa ni Maiduguri, ko to tun di adari ajọ amusẹya Multi National Joint Task Force, ti ibujoko rẹ wa ni orilẹede Chad.

Oṣu Karun un, ọdun 2017 ni wọn yan ọgagun Irabor Lucky lati rọpo Adeọṣun ni MNJTF, to si pada sile.

Oṣu Keje, ọdun 2018 ni wọn yan Adeọsun sipo adari to dimu titi di asiko yii, nibi to ti n mojuto eto ikọni ati agbeyẹwo isọwọ sisẹ awọn ọmọ ogun Naijiria.

Buhari gbe awọn ọmọ ogun ilẹ̀ mẹta ga:

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ Ogagun Lamidi Adeosun to jẹ oludari ẹka ikọni ati iṣẹ ṣiṣe di ọgagun agba pata lẹnu iṣẹ ogun.

Ipo tuntun yii ni o ga julọ lẹnu iṣẹ ologun lọwọ ni Naijiria ni eyi ti Ogagun Tukur Buratai to jẹ adari awọn ọmọ ogun ilẹ̀ Naijiria jẹ bayii.

Ileeṣẹ ọmọ ogun ilẹ̀ ni Naijiria naa ti fi ontẹ lu igbega awọn ọmọ ogun naa.

Adele alukoro fun ileeṣẹ ologun Naijiria, Ogagun Sagir Musa ṣalaye pe kii ṣe ọgagun Lamidi nikan ni aarẹ Buhari gbega lẹnu iṣẹ ologun nitori iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe paapa ni ariwa Naijiria.

Ileeṣẹ ologun tun ki Ogagun Buluma Biu to n dari ikọ ọmọ ogun Division & ati Lafiya Dole ni Maiduguri àti Ogagun AJ Danjibun ti ikọ ọmọ ogun 211 Demonstration Batallion ni Bauchi.

Ogagun Tukur Buratai to ti ṣiṣẹ ologun fun o le ni ọdun marundinlogoji paapaa ti ki àwọn ọgagun wọnyii ku oriire.

Ijọba Naijiria fidiẹ mulẹ pé Ogagun Tukur Buratai ṣi ni o n ṣiṣẹ adari awọn ọmọ ogun Naijiria lọ ati pe Ogagun Lamidi Adeosun yoo ṣi tẹsiwaju ninu ṣiṣe adari ẹka ikọni awọn ọmọ ogun ilẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCAN: Samson ni ọrọ awọn ajinigbe ti gba àpérò ní Naijiria