Tí mo bá tún ayé wá, ó wù mí kí n bí ju ọmọ 17 tí mo bí lọ

Jummai Ibrahim

Arabinrin Jummai Ibrahim to n gbe nilu Kano sọ fun BBC pe ti oun ba tun aye wa, o wu oun ki oun bi ju ọmọ mẹtadinlogun lọ, nitori pe ibukun lati ọdọ Ọlọrun ni ọmọ jẹ.

Jummai sọ pe ninu ọmọ mẹtadinlogun ti oun bi, meje ti ku lara wọn, to si ku mẹwaa; ọkunrin marun un, ati obinrin marun un.

Abilekọ naa sọ pe inu oun maa n dun pupọ ni ayajọ ọjọ bi eniyan ṣe pọ to laye, ti ori oun si maa n wu pe oun bi ọmọ to pọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àwa táa jẹ́ alágbàtọ̀ gan, èèyàn ni wá, ẹ ye ṣe wa bí ẹranko'

'Ayọ lo maa n jẹ fun mi pe mo bi to ọmọ mẹtadinlogun. Fun raa mi ni mo si bi wọn lai lo iṣẹ abẹ. Meje ti ku, ṣugbọn mẹwaa wa laaye bayii.'

'Ọgbọn ọdun sẹyin ni mo ṣegbeyawo, mo si ti ni ọmọ-ọmọ meji. Ọpọ to ba ri mi ko ni i mọ pe mo bi to ọmọ mẹtadinlogun.''

'Imọran mi si awọn to n pariwo pe awọn eniyan to wa laye ti pọju, ati pe ohun lo n fa aito ounjẹ ni awọn ibi kan, ni pe irọ patapata ni. Ibukun ni ọmọ jẹ, yoo si wu mi lati bi ju mẹtadinlogun lọ ti mo ba tun aye wa.''

Iyawo ile ni Jummai, diẹ lara awọn ọmọ rẹ to ti dagba si maa n wa iṣẹ ṣe lati pese ounjẹ ati owo fun oun ati ọkọ rẹ pẹlu awọn ọmọ to ku.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIya Woli: Ẹ̀mí ìjókíjó, Wòó, Ṣọ̀kí, Wojú, Ṣàkùṣákù, One Corner...jáde!

Jummai sọ fun BBC pe lara awọn ọmọ oun to ti kawe gboye ti wọn si n ṣiṣẹ wa.

Ipinlẹ Kano lo ni eniyan to pọ ju ni orilẹede Naijiria gẹgẹ bi akọsilẹ eto ikaniyan ọdun 2006 ṣe sọ. O ku diẹ ki wọn o pe miliọnu mẹrinla (13.6 million).