Nigeria Customs Service: Kò sí ǹkan tó jọ tòmátò tó ní májèlé ní Nàìjíríà'

Tomato Image copyright Getty Images

Igbakeji Oludari Ajọ Aṣọbode Naijiria, Anthony Ayalogu ti sọ pe ajọ naa ko mọ nipa tomato alagolo oni majele ti awọn eniyan kan sọ pe wọn ko wọ orilẹede Naijiria lati Iran.

O sọ eyi gẹgẹ bi esi si iroyin ti awọn ileeṣẹ iroyin kan gbe jade lọjọ kẹrinla, oṣu Keje pe ajọ Aṣọbode ti kilọ pe ki awọn eniyan ṣọra fun tomato alagolo onimajele to ti wa ni ọja.

Ninu ọrọ to ba BBC Igbo sọ, Ayalogu sọ pe ko si otitọ kankan ninu iroyin naa, ati pe ko ṣeeṣe fun tomato alagolo kankan lati wọ Naijiria lati ilẹ okeere nitori pe ofin ko faaye gba a.

"Ko si ọna ti yoo gba wọle ti a ko ni mọ, 'tori o tako ofin lati ko wọn wọle. Ti a ba wa ri ẹnikẹni to ko o wọle, o tumọ si pe fayawọ lo ṣe.''

Diẹ lara awọn iroyin to jade lopin ọsẹ to kọja sọ pe 'apoti ikẹru 'container' mẹfa lo ko tomato alagolo ti ọjọ ti lọ lori rẹ, ti ko si tun pojuowo, ti orukọ rẹ n jẹ 'Shirin Asal my tomato paste'' wọ Naijiria lati Iran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLílo òógùn apakòkòrò fún oúnjẹ l'éwu

Ọga Aṣọbode ọhun sọ pe ko ṣeeṣe fun ajọ naa lati ṣe iwadii iroyin naa nitori pe wọn ko sọ orukọ ọkọ oju omi to gbe e wọle tabi ọjọ ti wọn gbe e wọle.

Nigba ti BBC beere lọwọ Ayalogu pe bawo wa ni awọn eniyan ṣe n ri tomato alagolo ti wọn ko ṣe l'orilẹede Naijiria ra ni ọja, o sọ pe "mi o ni idahun kankan fun ibeere yii, amọ o ṣeeṣe ki wọn o ti wa ni ọja ka to o fi ofin de e.

Bi ọdun kan sẹyin ni ofin naa jade."

Awọn Iroyin ti ẹ le nifẹ si