Forceful Penetration: Bí ó bá ṣe obìnrin ló fi agídí mú ọ̀kùnrin bá a lò pọ̀ ńkọ́?

Ọkunrin ati Obinrin

Bi ọkunrin ba ni ibalopọ pẹlu obinrin lai gba aṣẹ lọwọ rẹ, ifipabanilopọ ni.

Ṣugbọn ti obinrin ba wa fi agidi mu ọkunrin lati ba a lo pọ nkọ? Ṣe ifipabanilopọ naa ni?

Kii ṣe ifipabanilopọ labẹ ofin ilẹ Gẹẹsi, ṣugbọn oluwadii kan ti sọ pe o yẹ ki wọn o ka a si ifipabanilopọ.

Dokita Siobhan Weare ti fasiti Lancaster University Law School kọkọ ṣe iwadii ifipabanilopọ l'orilẹede UK ni ọdun 2016 si 2017 laarin awọn ọrẹkunrin to le ni igba.

Iwadii to ṣẹṣẹ ṣe pẹlu ifọrọwanilẹnuwo fun awọn ọkunrin ọgbọn laarin oṣu Karun un, ọdun 2018 si oṣu Keje, ọdun 2019, lati mọ bi awọn ọkunrin ṣe n koju ibalopọ tipatipa.

Ọkan lara wọn ti a fi orukọ bo ni aṣiri, Josh, sọ pe nigba ti ololufẹ oun yoo kọkọ bẹrẹ si ni mu oun ni tipa-tipa lati ni ibalopọ, o maa n ṣe ara a rẹ l'eṣe, to si jẹ pe ọpọ igba ni wọn sare gbe e lọ sile iwosan fun itọju.

Àkọlé fídíò,

Kayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó

Koda, o ri awọn onimọ nipa ihuwasi eniyan ati arun ọpọlọ, ṣugbọn iyatọ ko sii.

"Nigba miran to ba de lati ibi iṣẹ, nkan akọkọ ti yoo kọkọ beere fun ni ibalopọ."

Àkọlé àwòrán,

Ǹjẹ́ bákan náà ní ǹkan rí ní gbogbo àgbáyé?

Ti mo ba kọ, yoo bẹrẹ si ni lu mi tabi fi nkan gba mi, debi wi pe ẹru maa n ba mi ti akoko ti yoo de lati ibiṣẹ ba ti n sunmọ."

Iṣẹlẹ kan ti mo ranti ni pe "mo ji l'oju orun ni mo ri i pe ololufẹ mi ti fi mamu gaari (handcuff) so ọwọ ọtun mi mọ ibusun wa. O si bẹrẹ si ni fi nkan lu mi ni ori."

Yatọ si eyi, o tun fi nkan miran so ọwọ rẹ keji, o si n gbiyanju lati fi ipa mu John ni ibalopọ.

Ṣugbọn John ko le ṣe oun to fẹ nitori pe o ti fi ara pa pupọ. O to ọgbọn iṣẹju ko too tu u silẹ. Ko si sọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò,

Helen Paul sọ idi tó fi gba orúkọ ní kékere

Igbagbọ John ni pe ayipada yoo wa nigba to l'oyun. Ṣugbọn lẹyin oṣu diẹ ti o bimọ, John tun ji lọjọ kan, lo tun ri i pe o ti de e mọ ibusun.

Lẹyin naa "lo fi ipa fun un ni oogun amaraji pepe mu."

"Mi o le ṣe ohunkohun nipa rẹ."

Gbogbo igba ti John ba gbiyanju lati sọ fun awọn eniyan, wọn kii gbagbọ.

"Ọpọ igba ni wọn ti beere lọwọ mi pe, kilode ti mi o fi ile silẹ fun. Mi o le fi silẹ, nitori pe ile ti mo ra fun awọn ọmọ mi ni. Ati wi pe mo ti naa ọpọlọpọ owo sori ibaṣepọ naa."

Diẹ lara iriri John fi ara jọ nkan ti awọn ọkunrin yooku ti Dokita Weare fi ọrọ wa l'ẹnuwo.

Iwadii rẹ fihan pe:

Oju maa n ti awọn ọkunrin lati ro iru ẹjọ bẹ ẹ sita - wọn le fi ẹjọ iwa buruku iyawo wọn sun o, ṣugbọn wọn ko ni i sọ pe o n fi tabi fẹ ẹ fi ipa ba wọn lo pọ.

O maa n mu wahala ba bi ọkunrin ṣe le ṣe daada si lasiko ibalopọ, tabi ko maa ronu lati gba ẹmi ara a rẹ.

Kii ṣe gbogbo igba ti nkan ọmọkunrin ba dide lo tumọ si pe ọkunrin naa fẹ l ni ibalopọ.

Ọpọ ọkunrin ni ololufẹ wọn maa n fi agidi mu lati ni ibalopọ lasiko ti iru ọkunrin bẹ ẹ ba ti mu ọti yoo.

Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ sii