NAF: Iléeṣẹ́ ọmọ ogun dá Bashir tó ri owó he lọ́lá

Image copyright @NAF
Àkọlé àwòrán Naijiria bu ọla fún ọmọ ogun to da owo to ri he pada

Ile iṣẹ ọmọ ogun ofurufu Naijiria ti ṣe koriya fun akinkanju ọmọ ogun Bashir Umar.

Bashir Umar to ri ẹgbẹrun lọna mẹtadinlogoji owo pọun ilẹ okeere he ni papakọ ofurufun ti Kano ni wọn ti da lọlaMo mọ̀ọ́mọ̀ dá €37,000 ti mo rí he padà ni -Ọmọ ogun Bashir.

Ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu Naijiria fun Bashir Umar ni igbega ọdun meji lẹyin to gbe owo to ri he ni ọja Hajj pada fun ẹni to ni.

Iṣe akọni ọmọluwabi to ṣe yii jẹ ki Aarẹ Muhammadu Buhari to n tukọ Naijiria lasiko yii gboriyin fun Bashir.

Aarẹ ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii ọdọ ti ko wọpọ lasiko yii, to jẹ awokọṣe rere to ni ootọ inu.

Ni ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kejila ni wọn ṣe ayẹyẹ idanilọla fun akinkanju ọdọmọkunrin yii pe o kare!.

Aarẹ Buhari parọwa fun awọn ọdọ Naijiria lati farawe ọkunrin yii ki gbogbo wọn maa fi ootọ inu ṣe iṣẹ wọn bi o ti yẹ.

Bayii Bashir Umar to jẹ Air Craft man ti fo ipele meji (Lance Coporal) bọ si ipo Coporal ni eyi to le gbaa to ọdun meje lẹnu iṣẹ ologun ko to de tẹlẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÉégún tó wà nídí Yoruba Bollywood, Samo Baba f'ojú hàn o!

Bakan naa ni ọgagun Sadique Abubakar to ṣoju adari wọn nibi eto naa fun Bashir ni lẹta o kare ọmọ ọdọ rere nitori iwa to hu yii jẹ ọpakutẹlẹ awọn ọmọ ogun ofurufu ni Naijiria.

Ẹbi, ara, ọrẹ, ojulumọ ati awọn alajọ ṣiṣẹ pọ Bashir Umar ni wọn wa nibi idanilọla naa.

Wọn fi ọkọ ofurufu ologun gbe Bashir lati Kano lọ si olu ileeṣẹ ologun ni Abuja lati ṣe koriya fun un.

Wo itan igbesi aye Bashir Umar:

A bi Bashir Umar ni ọjọ kinni, oṣu kẹfa, ọdun 1995 sinu ẹbi Mallam Bashir Abdulmumuni ati Salamotu Aliyu.

Omọ ijọba ibilẹ Maiha nipinlẹ Adamawa ni Bashir.

Bashir lọ si ile iwe alakọbẹrẹ Maksha Nursery and Primary School lọdun 1999 si 2005.

Ko to lọ si Tijjani Boloni College fun ẹko keu ati imọ lọdun 2006 si oṣu kẹsan an, ọdun 2009.

O tun lọ si ile iwe girama ti ijọba Maiha Government Secondary school to ti ṣe idanwo iwe mẹwaa lọdun 2012..

O lọ si ile ẹkọ Gbogboniṣe Adamawa ni Yola nibi to ti kọ ẹkọ nipa idena iwa ọdaran lawujọ lọdun 2016.

Bashir darapọ mọ awọn ọmọ ogunn ofurufu lọjọ kinni, oṣu kẹjọ, ọdun 2016 lẹyin to kẹkọ nipa iṣe ologun yanju ni Kaduna.

O wa ni ẹka NADC to jẹ ti Mobile Air Defence Team (MADT) ni MAKIA nipinlẹ Kano.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó