Shiite: Èmi kò ní kí Shiite má ṣe ẹ̀sìn wọn o -Muhammadu Buhari

Image copyright others
Àkọlé àwòrán Emi ko ni ki ẹ dẹkun ẹsin Shiite o - Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari ti kedé pé oun ko ni ki ẹlẹsin Shiite ma sin ẹsin to wu wọn.

Aarẹ Buhari ni iṣẹ oun yatọ si ti adajọ ile ẹjọ ati pe ẹlẹsin Shiite kọ ni adajọ dajọ funÀgùnbánirọ̀ akọ̀ròyìn Channels náà ti dágbére fáyé látààrí ìkọlù Shiite l'Abuja .

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Buhari mọ pe awọn ẹlẹsin Shiite pọ ni Naijiria ti wọn n gbe ni alaafia

Aarẹ Buhari to n tukọ orilẹ-ede Naijiria ni Islamic Movement of Nigeria ni ọrọ aṣẹ adajọ n ba wi kii ṣe ẹlẹsin ShiiteIkọ̀ aláàbò Nàìjìríà dojú kọ Shiite .

Opọlọpọ ẹmi ati dukia lo ti sọnu lati igba ti awọn ẹlẹsin Shiite ni ariwa Naijiria ti bẹrẹ ifẹhonuhan lori olori wọn El Zakzakky to wa ni atimọleỌlọ́pàá mú 115 ẹlẹ́sìn Shiite.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ̀mí sùn níbi ìkọlù Shiite àti ọlọ́pàá

Lẹyin ọpọlọpọ nkan to ti ṣẹlẹ lori Ibrahin el Zakzakky ti wọn fi si atimọle ni igbẹjọ ile ẹjọ ni ki wọn kede awọn IMN gẹgẹ bii agbesunmọmi ni NaijiriaMo ṣe tán láti kú tọmọ taya bí wọn kò bá fi El-Zakzaky sílẹ̀ - ọmọ ẹgbẹ́ Shiite .

Garba Shehu to jẹ olubadamọran fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori eto iroyin ṣalaye fun BBC pe aṣẹ ile ẹjọ ko sọ pe ki awọn ẹlẹsin Shiite ma sin ẹsin wọn bikoṣe pe fun awọn IMN.

Garba Shehu ni akọsilẹ ile ẹjọ lo fihan pe iṣe IMN ti gba ọpọ ẹmi ati dukia ni eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ ni ilu to lọba ati ijoye, eyi to ṣokunfa igbẹjọ yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionShiite: Tinúbú, bá Buhari sọ̀rọ̀ kó tú ZakZaky sílẹ̀ kó tó pẹ́ jù

Garba shehu tẹpẹlẹ mọọ ninu ọrọ rẹ fun BBC pé aarẹ Buhari ni ọpọlọpọ ẹlẹsin Shiite lo wa ni orilẹ-ede Naijiria ti wọn n gbe ni alaafia ti wọn ko ba ijọba ja rara.

O ni ko si ẹni to si n yọ awọn naa lẹnu nibi iṣẹ ati ilana ẹsin wọn.

Ati pe: ko si ẹni to ni ki ẹnikẹni ma sin Shia to ba fẹ sin rara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria Pensioners: Wàhálà àyẹ̀wò iwé ìfẹyinti yì ti pọ̀jù

Akọsilẹ Ile Ẹjọ lori IMN labẹ El Zakzakky:

Akọsilẹ ile ẹjọ fihan pe Adajọ Tionye Maha ni ko si idi kankan fun ẹnikẹni lati da ilu ru mọ lorukọ ẹgbẹ kankan.

Ati pe fifi ofin de IMN waye lẹyin ti ile ẹjọ gba iwe ipe fun aṣẹ lati ọdọ ijọba apapọ ki alaafia le jóba lasiko yii.

Akosilẹ naa ni ile ẹjọ ti paṣẹ fun minista fun eto igbẹjọ ni Naijria lati kede aṣẹ ijọba ati tawọn ile iṣẹ iroyin mejeeji.

Iwọde awọn Shiite yii bẹrẹ ti wọn fi n beere pe ki ijọba fi olori wọn El Zakzakky to ti wa latimọle lati ọdun 2015 silẹ.

Opọ ẹmi lo ti sọnu si iwọde wọnyii ni Abuja lai yọ ọga agba ọlọpaa silẹ ati agunbanirọ pẹlu awọn ẹlẹsin Shiite silẹ.

Image copyright @zakzakky
Àkọlé àwòrán Awọn Shiite ni awọn ṣetan lati fi ẹmi wọn dii

Aṣẹ ti wa lati ọdọ ijọba pe ki wọn kede IMN ni ẹgbẹ agbesunmọmi bayii.

Kete ti wọn ba ti mu aṣẹ yii ṣẹ lo ti tumọ si pe IMN ni ikeji ti wọn maa kede ni agbesunmọmi yato si ti IPOB nile Igbo.

Adajọ Abubakar Malami to jẹ minista eto idajọ tẹlẹ ko ti i sọrọ lori igbesẹ ti yoo gbe lasiko yii.

Ṣugbọn iwe ilana ofin Naijiria ni abala 174 gbe agbara fun minista eto idajọ lati pese aabo to yẹ fun ilu ati ẹtọ ọmọniyan ni eyi ti awọn kan gba pe o fi le ṣi fi El Zakzakky atawọn miran si atimọle.

Loju awọn eniyan miran, ijọba Naijiria ko bọwọ fun ofin to ni.

Nitori pe adajọ ti ni ki wọn fi Dansuki Sambo ati El Zakzakky silẹ tẹlẹ.

Awọn mejeeji n beere fun ominira lati lọ fun itọju ara wọn nilẹ okeere.

Wọn ti sun igbẹjọ naa di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu keje ọdun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionN100,000 Nairà mà ni Dino gbé dání lójú agbo, kò náwó yàlà-yòlò - Ayefele