2019 Hajj: NAHCON ní Nàìjíríà pàdánù èèyàn 5 láti ipàsẹ̀ àìsàn

Awọn arinrinajo ni Mecca

Oku di marun un je Olorun nipe ninu irinajo Hajj todun 2019.

Ajọ to n mojuto irinajo Hajj ni Naijiria, National Hajj Commission of Nigeria, NAHCON, ti fidi rẹ mulẹ pe ọmọ orilẹ-ede Naijiria marun un lo ti ku lara awọn to rinrinajo lọ silẹ mimọ Mecca.

Lara awọn to ku ọhun ni ọkunrin meji ati obinrin mẹta.

Ọkan lara wọn ku si ilu Madina, nigba ti awọn mẹrin toku ku si ilu Makkah.

Ninu atẹjade kan ti Alaga igbimọ eto ilera ninu ajọ NACHON, Dokita Ibrahim Kana fi sita, to si tẹ BBC Yoruba lọwọ, ajọ naa sọ pe oriṣiriṣi aisan bii aisan ọkan ati ẹdọforo lo pa awọn eeyan to ku naa.

Awọn meji lara awọn eniyan to ku ọhun, ọkunrin kan ati obinrin kan wa lati ipinlẹ Katsina.

Nigba ti awọn mẹta tó kù si wa lati ipinlẹ Sokoto, Nassarawa ati Kano.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Nigba ti awọn mẹta tó kù si wa lati ipinlẹ Sokoto, Nassarawa ati Kan

Kana fi kun ọrọ rẹ pe, arinrinajo to le ni ẹgbẹrun mẹwaa lati Naijiria lo ti gba iwosan ni awọn ileewosan orilẹ-ede Naijiria to wa ni Makkah ati Madinah.

Bakan naa lo sọ pe, eeyan mejidinlaadọfa ni wọn gbe lọ si awọn ileewosan orilẹ-ede Saudi fun itọju to l'agbara nitori pe, aisan wọn le pupọ. Ṣugbọn, pupọ lara wọn ti kuro nileewosan bayii.

Image copyright @Ramdog1980
Àkọlé àwòrán Pupọ lara wọn ti kuro nileewosan bayii

Ajọ naa si ti gba awọn arinrinajo ni imọran lati yago fun rínrìn ninu oorun, ki wọn si maa mu omi daadaa, ki wọn o si maa wọ aṣọ to fẹlẹ.