NCDC: Kò sí àrùn 'Monkey Pox'ní Naìjiria- NCDC

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ko si arun yii ni Naijiria!

Ajọ to n mojuto ọrọ itankalẹ arun ni Naijiria, Nigeria Centre for Disease Control (NCDC) ni ki awọn eniyan má bẹru.

NCDC ni iroyin ofege lo n tan kiri lasiko yii pe arun ọbọ ti wọn n pe ni Monkey Pox ti wa ni awọn ipinlẹ bii Eko, Rivers ati Akwa Ibom.

Wọn ni rioyin yii a kan fa ẹru ati iporuru ọkan fawọn eniyan ni nitori pe irọ funfunf balau ni.

Ajọ NCDC ti wọn n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ti Iwọ oorun ilẹ̀ Adulawọ ni lọdun 2017 ni awọn kọkọ gba iroyin iṣẹlẹ akọkọ arun yii ni eyi ti awọn si n ṣọ kaakiri orilẹ-ede.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBlood Donor Day: Láìsí ẹ̀jẹ̀ kò sí ẹ̀mí

Ajọ NCDC ni lati bii ọjọ melo kan lawọn ti n gba ifitonileti iṣẹlẹ arun monkey pox lawọn ibudo kọọkan ni eyi ti awọn ti n ṣamojuto si bayii.

Ati pe iṣẹlẹ afurasi mẹta lo wa nilẹ ti awọn n ṣayewo le lori bayii ni eyi ti wọn fi soju opo itakun agbaye wọn pe wọn ri ni ipinlẹ Eko ati Rivers.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo bi ọmọbirin yii se n sun ẹjẹ

Ajọ NCDC ni irọ ni pe awọn kan ti gbẹmi mi latari arun monkey pox yii.

Ajọ iṣọkan to wa fun ilera agbaye, WHO ni arun monkey pox maa n wa ni aaringbungbun ati iwọ oorun ilẹ Adulawọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀàrùn arunmọléegun ti lóògùn ti wà báyìí

Ajọ NCDC fi atẹjade kan sita lọjọ Eti yii ti wọn fi kilọ gbigbe iroyin ẹlẹjẹ paapaa nipa ilera ti ko dara rara.

Wọn ni awọn ṣetan lati maa dahun ibeere lori ohunkohun to ba ru ẹnikẹni loju dipo ki wọn maa gbeiroyin ofege kiri eyi to le fa ibẹru ati ipaya fawọn ara ilu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPainter: Samuel ni ìdàgbàsókè Nàìjíríà ló jẹ òun lógún!