Divorce: Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mẹ́tàdínlógún ká nítorí ààlè yíyàn

Aworan ibalop ati abo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mẹ́tàdínlógún ká nítorí ààlè yíyàn

Ile ẹjọ ibilẹ kan ni agbegbe Igando nilu Eko ti tu igbeyawo ọdun mẹtadinlogun ka.

Ọkọ iyawo, Chike Aroh to jẹ ẹni ọdun marundinlaadọta sọ fun ile ẹjọ wi pe iyawo oun, Chioma Aroh maa n gbe awọn aale wa si ile ti awọn n gbe, ti wọn si jọ maa n ni ibalopọ lori ibusun awọn.

Chike nigba to n rojọ nile ẹjọ sọ pe awọn ọmọ oun sọ fun oun pe iya awọn maa n gbe ọkunrin wa sile, ti awọn mejeeji si jọ maa n tilẹkun yaara ibusun pa mọra wọn.

Chike sọ fun ile ẹjọ pe "Nigba ti mo bi leere, ko ri idahun to ni itumọ fun mi."

"O ti le ni oṣu mejila to ti jẹ ki n ba oun ni ajọṣepọ gbẹyin, ṣugbọn ọfẹ lo n fun aale rẹ."

Lara awọn ẹsun ti Chike fi kan iyawo rẹ Chioma ni pe, o maa n ja ija igboro, to si tun jẹ ọlẹ ti kii dana ounjẹ tabi f'ọṣọ fun oun.

Bakan naa lo sọ pe o jẹ ọmuti paraku, eyi to maa n mu ki o ṣi iwa hu.

Ati wi pe o maa n fi ọbẹ, igo ati awọn nkan oloro mi i dun kooko mọ ẹmi oun.

Chike bẹ ile ẹjọ lati tu wọn ka ko to o di wi pe 'iyawo oun yoo pa oun'.

Ileeṣẹ akoroyin jọ NAN, jabọ pe Aarẹ ile ẹjọ naa, Ọgbẹni Kayode Koledoye, ninu idajọ rẹ sọ pe o fi oju han lati ara ọrọ ti ọkọ sọ, ati bi iyawo ti wọn fi ẹsun kan ṣe kọ lati yọju sile ẹjọ ni gbogbo asiko ti igbẹjọ n waye, pe igbeyawo naa ti fi ori ṣọnpọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNo reception wedding: Adewale ni àpèjẹ kò ṣe pàtàkì sí òun

"Lati igba ti a ti bẹrẹ igbẹjọ yii, ẹni ti wọn fi ẹsun kan ko yọju sile ẹjọ rara, nitori naa, titu ni ile ẹjọ yoo tu igbeyawo naa ka."

Lẹyin eyi ni Adajọ sọ pe igbeyawo naa ti di titu ka, to si paṣẹ fun ọkọ iyawo, Chike, lati san ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira fun Chioma gẹgẹ bi owo ipinya, eyi ti yoo fi bẹrẹ igbeaye tuntun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfrica Eye: Ohun tí ọ̀rẹ́ mi fí sórí 'Social Media'ló wọ̀ mí lójú- Grace

Related Topics