Ondo Kodnap: Ọmọ ogún ọdún sọnù, wọn jí ìyàwó, ọmọ àti awakọ̀ ọba gbé l'Ondo

Awọn ọkunrin to gbe ibọn dani.
Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ogún ọdún sọnù, wọn jí ìyàwó, ọmọ àti awakọ̀ ọba gbé l'Ondo

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni wi pe mọbinrin, ọmọ ogun dun kan tun ti di awati nile ijọsin kan nipinlẹ Ondo.

Ọmọbinrin naa, Faith Aluko ti wọn lo wa ni ipele to kẹhin ni fasiti, la gbọ wi pe o di awati lasiko ti oun ati baba rẹ lọ sile ijọsin kan ni oju ọna to lọ si papak ofurufu ilu Akurẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Femi Joseph to fidi iroyin na mulẹ fun BBC sọ pe ọmọ naa pada jade nile ijọsin lasiko to ni oun fẹ ẹ tọ. Ṣugbọn wọn ko ri i ko pada lati ọjọ Aiku.

Awọn ileeṣẹ iroyin kan l'abẹle sọ pe ọmọbinrin naa sọ fun awọn oṣiṣẹ alaabo to wa l'ẹnu ọna ile ijọsin Mountain of Fire ọun,pe oun fẹ ẹ ra paadi nkan oṣu nile itaja kan to wa l'ẹgbẹ ṣọọṣi naa.

Iroyin miran to tun tẹ wa lọwọ ni pe, awọn agbebọn kan ti ji oṣiṣẹ ajọ to n ṣeto idanwo ileewe girama, WAEC, kan, Adebayo Gbenga ati awọn mẹta miran gbe ni ipinlẹ Ondo.

Oríṣun àwòrán, @NigerianPolice

Iṣẹlẹ naa la gbọ pe o waye nilu Oba Akoko ni oju ọna to lọ lati Ọwọ si Ikarẹ-Akoko nijọba ibilẹ Akoko South West.

Iwe iroyin abẹle kan nipinlẹ Ondo, Sunshine Truth sọ pe lasiko ti Gbenga ati ọrẹ rẹ kan n gbe ọmọ rẹ lọ si fasiti Adekunle Ajasin to wa ni Akungba-Akoko ni wọn pade agbako.

Àkọlé fídíò,

Ohun mẹ́jọ tóo ní láti mọ̀ bí o bá fẹ́ lọ ilé ọdun

A gbọ pe ọrẹ Gbenga, ati ọmọ Gbenga ti wọn n gbe lọ si ileewe raaye salọ nitori bi wọn ṣe tete raaye ṣilẹkun ọkọ, ti wọn si sawọ inu igbo.

Ṣugbọn, ọwọ tẹ Gbenga ati awọn mẹta miran ti awọn naa n lọ ninu ọkọ wọn, ti wọn si ko gbogbo wọn wọ inu igbo lọ.

Àkọlé fídíò,

Àwọn aránṣọ yarí pé gbogbo ẹ̀bi kìí ṣe tàwọn, díẹ̀ wà lọ́wọ́ àwọn oníìbárà náà

Wọn ni awọn ajinigbe naa ti kan si ẹbi Gbenga ati ibi iṣẹ rẹ nilu Akurẹ, ti wọn si n beere fun ogun miliọnu Naira ki wọn o to o le tu u silẹ.

Àkọlé fídíò,

Ǹkan tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn mí kí n tó bẹ̀rẹ̀ orin ìfèdèfọ̀ rèé- Testimony Jaga

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Femi Joseph to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC sọ pe wọn tun ji iyawo, awakọ ati awọn ọmọ Ọba ilu Odigbo nipinlẹ Ondo, Ọba Rufus Akinrinmade gbe.

A gbọ wi pe ọgọrun ẹgbẹrun Naira gẹgẹ bi owo ti wọn yoo gba ki wọn o to o tu wọn silẹ.

Joseph sọ pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ lori awọn ijinigbe naa, ti awọn yoo si ri daju pe awọn doola awọn ti wọn ji gbe.