Sagamu Interchange - Ìjọba yóò ti afára Sagamu pa nítorí ìjàmbá iná

Ajoku ọkọ agbepo to jona ni Sagamu

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán,

Sagamu Interchange - Ìjọba yóò ti Afára Sagamu pa nítorí ìjàmbá iná

Ileeṣẹ alaabo oju popo ijọba apapọ, FRSC ti kede wi pe wọn yoo ti ori afara ilu Sagamu pa fun asiko kan lati ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2019.

Eyi n waye nitori ijamba ina kan to waye l'abẹ afara naa lọjọ ọdun Keresimesi.

Àkọlé fídíò,

Christmas & Border Closure: ìrẹsì dí góòlù fún Kérésì 2019

Ọga agba ajọ FRSC nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Clement Oladele sọ fun ileeṣẹ akoroyinjọ Naijiria, NAN, wi pe ijamba ina naa lo ṣokunfa igbesẹ yii.

Ati pe, ohun lo mu ki awọn o ranṣẹ pe awọn amoju ẹrọ ileeṣẹ ijọba apapọ to wa fun Isẹ ode ati ile gbigbe lati wa ṣe ayẹwo afara oloke naa nitoi bi ijamba ina naa ṣe lagbara.

Àkọlé fídíò,

Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

"Abọ ayẹwo awọn onimọ ẹrọ naa lo fihan wi pe afara naa ko dara fun lilo awọn awakọ titi wọn yoo fi ṣe atunṣe si."

NAN jabọ pe awọn ọkọ agbepo mejeeji to n lọ lati ilu Eko si Ibadan kọlu ara wọn labẹ afara naa to wa nitosi ileewosan pajawiri ti ajọ FRSC nilu Sagamu.

Wọn ni ere sisa to pọju, eyi to mu ki wọn o gbina pẹlu epo to wa ninu awọn ọkọ naa kọja keremi.

Àkọlé fídíò,

Police Brutality: Ojú mi rí tó lọ́wọ́ ọlapàá nítorí Múrí màrùn ún- Adebayo Olaide

Wọn ti wa rọ awọn araalu lati yẹra fun afara naa paapaa awọn to n lọ si ilu Sagamu, Ijẹbu-Ode, Ore, Benin ati awọn ilu miran.

Àkọlé fídíò,

Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ

Oladele gba awọn awakọ to n lo afara naa lati tẹle ilana naa tuntun yii fun lilo rẹ:

  • Awọn to n bọ lati ọna Ijẹbu-Ode, ki wọn o ya gba ẹyin ileewosan pajawiri FRSC lati lọ jasi oju ọna to lọ si Ibadan.
  • Lẹyin naa ni ki wọn o lọ ya pada nitosi ilu Ogere lati tẹsiwaju ninu irinajo wọn silu Eko.
Àkọlé fídíò,

Ǹjẹ́ o mọ pàtàkì igi tó wà ní àyíká rẹ bí?

  • Fun awọn to n bọ lati ilu Abeokuta, to si n lọ si ọna Ijebu-Ode ati ila oorun Naijiria lati maa lo afara naa.
  • Dipo bẹẹ, ki wọn o ya ti wọn ba ti kọja ileeṣẹ Nestle si ọna to lọ silu Eko.
Àkọlé fídíò,

Christmas: Jesu ni ọjọ́ ọ̀la àti ibi ìyanu mi- Jaga

  • Lẹyin naa ni ki wọn o ya pada ni Kara-Sagamu, ni kete ti wọn ba kuro ni ọgba ileeṣẹ Berger Construction to wa ni Sagamu.
  • Lati ibẹ, Oladele ni ki wọn o tẹsiwaju irinajo wọn si opopona Sagamu- Ijebu Ode - Ore - Benin.
Àkọlé fídíò,

Mo n wa'yawo - Falz