Àlùfáà ìjọ Redeem àti ọmọ rẹ̀ méjì kú sílé ìgbafẹ́ kan lásìkò Kérésì

Oloogbe Diya ati ọmọ rẹ, Comfort

Oríṣun àwòrán, facebook

Àkọlé àwòrán,

Gabriel Diya ati ọmọ rẹ, Comfort ku si ile igbafẹ kan ni Costa del Sol

Awọn eniyan ti bẹrẹ si i ṣe idaro alufaa ijọ Redeemed Christian Church of God, ati ọmọ rẹ meji to ku sinu odo iwẹ nile igbafẹ kan ni Costa del Sol l'ọjọ Aisun ọdun Keresi.

Gabriel Diya, ẹni ọdun mejilelaadọta, ati ọmọ rẹ obinrin, Comfort Diya, ọmọ ọdun mẹsan an, to fi mọ ọmọ rẹ ọkunrin, Praise Emmanuel-Diya, ọmọ ọdun mẹrindinlogun ku.

Wọn doloogbe lẹyin ti wọn mu omi yo ninu odò iwẹ igbalode to wa ni ile igbafẹ Club La Costa, nitosi Fuengirola ni orilẹ-ede Spain.

Awọn ọlọpaa sọ pe awọn n ṣe iwadii ẹsun wi pe ọmọbinrin naa lo wa ninu ewu, ti awọn meji yooku naa si padanu ẹmi wọn lasiko ti wọn n gbiyanju lati doola rẹ.

Ijọ ti Ọgbẹni Diya ti jẹ alufaa sọ pe awọn ba ẹbi awọn oloogbe kẹdun.

Ijọ RCCG, ninu ikede kan lori Facebook sọ pe: "Pẹlu ẹdun ọkan, a na ọwọ ibanikẹdun wa si ẹbi, ijọ,ọrẹ, ati awọn alajọṣiṣẹpọ Alufa Agbegbe, Gabriel Diya, to jalaisi, pẹlu ọmọ rẹ meji... ninu iṣẹlẹ to bani ninu jẹ kan to waye lasiko ti wọn lọ fun isinmi l'orilẹede Spain.

Oríṣun àwòrán, facebook

Àkọlé àwòrán,

Oloogbe Diya jẹ alufaa ijọ RCCG ni ila oorun ilu London

Ijọ naa sọ pe Ọgbẹni Diya tun jẹ alufaa ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi kan, Open Heavens. Orilẹ-ede Naijiria ni ẹgbẹ naa ti bẹrẹ, ṣugbọn Diya jẹ adari ti agbegbe Charlton, nilu London.

Iyawo, Olubunmi Diya, ati ọmọbinrin kan lo gbẹyin oloogbe Diya.

Ọkan lara awọn aladugbo idile Diya sọ fun ileeṣẹ iroyin PA pe, "ibanujẹ lo jẹ fun oun nigba t'oun gbọ iroyin iku naa, to si ṣapejuwe idile Diya gẹgẹ bi eyi to "gba ẹsìn daada, ni ọyaya, ko ni mọra, to si ni irẹlẹ".

Lara Akins, lasiko to n sọrọ niwaju ita ile rẹ ni Charlton sọ pe "Iku wọn ba gbogbo eniyan ni ojiji, nitori pe eniyan daadaa ni wọn".

Ọgbẹni Diya ati ọmọ rẹ obinrin ni iwe igbeluu orilẹ-ede Britain, nigba ti ọmọ rẹ ọkunrin ni ti Amẹrika.

Àkọlé fídíò,

Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Ninu atẹjade kan l'Ọjọbọ, awọn alaṣẹ ile igbafẹ Club La Costa World sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ ibanujẹ fun awọn".

Ati wi pe awọn yoo "tẹsiwaju lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn alaṣẹ to n ṣewadi iṣẹlẹ buruku naa".

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Ọpọlọpọ odò iwẹ igbalode ni ile igbafẹ Club La Costa ni

Ṣugbọn ṣaa, wọn ni awọn ti ṣi odò iwẹ pada fun lilo awọn onibaara wọn lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ti fun wọn ni aṣẹ lati ṣe bẹ ẹ.

Akọroyin abẹle kan, Fernando Torres, sọ fun BBC pe iṣẹlẹ naa jẹ ibanujẹ.

Àkọlé fídíò,

Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ

"Awọn oṣiṣẹ ile igbafẹ naa gbọ ti awọn eniyan n pariwo, wọn si gbiyanju lati ṣe itọju pajawiri, CPR, fun wọn, ṣugbọn wọn ko le e ran wọn lọwọ mọ."

"Koda, awọn dokita pajawiri gbiyanju fun ọgbọn iṣẹju si marundinlogoji, ṣugbọn ẹpa ko b'oro mọ.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ki Olorun dẹ ilẹ̀ fun ẹni rere to lọ, ki O tu awọn ẹbi to ku ninu ni adura ti ọpọ n gba.

Àkọlé fídíò,

Police Brutality: Ojú mi rí tó lọ́wọ́ ọlapàá nítorí Múrí màrùn ún- Adebayo Olaide