Ọ̀gá ọlọ́pàá tó wà ní 'Check Point' kàgbákò ikú òjijì lọ́wọ́ awakọ̀ l'Eko

Ami idanimọ ọlọpaa Naijriia Image copyright Getty Images

Inu ibanujẹ ni mọlẹbi Ripẹtọ Edighere Orhewere, ọga ọlọpaa ti awakọ akero kan fi ọkọ pa ni agbegbe Agbara nipinlẹ Eko.

Oloogbe Orhewere, to jẹ ẹni aadọta ọdun, ni iwe Iroyin jabọ pe oun ati awọn akẹẹgbẹ rẹ kan duro si kọọrọ kan lati ṣọ adugbo ni Agbara, ni awakọ danfo naa sọ ijanu ọkọ nu nitori ere asapajude, to si kọlu ọlọpaa naa lati ẹyin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMobile Wash: iṣẹ́ fífọ́ mọ́tò tà ni mó yàn láààyò- Slay Mama

Wọn ni niṣe ni awakọ naa salọ, to si fi ọkọ rẹ silẹ sibi ti iṣẹlẹ yii ti waye.

Gbogbo igbiyanju awọn akẹẹgbẹ ọlọpaa naa lati ri i mu lo jasi pabo ni eyi to pada ja si iku fun agbofinro naa.

Iroyin sọ pe oju ẹsẹ ni Ọga ọlọpaa naa, to jẹ baba ọlọmọ meje, ku nitori pe irin to wa niwaju ọkọ naa wọ ọ ninu egungun ẹyin ati ibadi rẹ.

Nibayii, wọn ti gbe oku rẹ lọ si ile igbokupamọ si to wa ni ileewosan Gbogboogbo ilu Badagry.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFarms to You: Irú ajílẹ̀ wo ló yẹ fún lílò lásìkò yìí- Aisha

A gbọ wi pe awọn ọlọpaa tọ ipasẹ ẹni to ni ọkọ, oun lo si ibi ti wọn juwe ile awakọ naa fun wọn.

Ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi de ibẹ, awakọ naa ati ẹbi rẹ ti ko kuro ni ile naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Bala Elkana sọ fun awọn akọroyin pe, wọn ṣi n wa awakọ naa to salọ.

Kọmiṣọnna ọlọpaa, Hakeem Odumosu, ni ibanujẹ lo jẹ fun awọn agbofinro pe wọn maa n padanu ẹmi wọn lẹnu iṣẹ.

O ni o di dandan ki ajọ agbofinro ṣe ẹyẹ ikẹyin fun awọn olọpaa bii ti ẹ to ku loju iṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria's Under-19:Ẹ wo bí Ikọ̀ Cricket Naijiria ṣe mi àgbáyé titi

Ati pe awọn mọlẹbi rẹ le bẹrẹ si ni ṣeto riri ajẹmọnu oloogbe gba lẹyin isinku.

Odumosu fi idaniloju han pe ọwọ yoo tẹ ọkunrin awakọ naa laipẹ laijinna.

Related Topics